Nigeria Independence Day: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ àyájọ́ ọdún òmìnira ní ìpínlẹ̀ Oyo

Àwọn èèkàn ìpínlẹ̀ Oyo ṣàjọyọ̀ ọdún òmìnira ìkọkàndínlọ́gọta Naijiria pẹlu àwọn ènìyan rẹ.

omo ogun
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun ti ṣetan lati yan bi ologun ni ipinlẹ Oyo
igbakeji gomina
Àkọlé àwòrán, Onimọ ẹrọ Rauf Olaniran to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ti ṣetan lati lọ yẹ awọn ọmọ ogun to n yan fanda wo ni Adamasingba
Igbakeji gomina
Àkọlé àwòrán, Ogbẹni Rauf Olaniyan ti n yan lọ ṣabẹwo saarin awọn ọmọ ogun ni ipinle Oyo
ọmọde
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun 'Brigade' naa wa nikalẹ ni papa iṣere Adamasingba ni Mọkọla ni Ibadan fun ayẹyẹ ayajọ ominira Naijiria tọdun 2019
Awọn Oba
Àkọlé àwòrán, Awọn ori ade lati Ibadan ati agbegbe rẹ naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ayajọ ọdun ominira Naijiria loni
akekoo
Àkọlé àwòrán, Awọn akẹkọ ile iwe girama kaakiri ipinlẹ Oyo naa wa nibi ayẹyẹ ayajọ ominira to ṣẹlẹ ni ilu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo
agbalẹ
Àkọlé àwòrán, Awọn iya agbalẹ ti wọn n tun papa iṣere Adamasingba ṣe naa fun oju lounjẹ nibi ayajọ ominira ọdun mọkandinlọgọta Naijiria ni Ibadan
olopaa
Àkọlé àwòrán, Wamu ni àwọn agbofinro duro ni papa iṣere Adamasingba nibi ayajọ ominira Naijiria ti ipinlẹ Oyo n ṣe
stadium
Àkọlé àwòrán, Ẹsẹ ko gbero ni papa iṣere Lekan Salami nibi ti igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ti ṣoju gomina Seyi Makinde nibi ayẹyẹ ayajọ ominira Naijiria tọdun 2019.
omo ogun
Àkọlé àwòrán, A ju ara wa lọ, ijakadi kọ ni ọrọ awọn to n yan bi ologun ni papa iṣere Adamasingba ni Naijiria ti wọn yọ ayajọ ọjọ ominira Naijiria.
ẹgbẹ osise
Àkọlé àwòrán, Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ loriṣiiriṣii ni wọn wa nikalẹ nibi eto akanṣe lati fi ranti iṣẹ awọn akọni Naijiria ti wọn jija ominira 1960
ami ẹyẹ
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn ami ẹyẹ ti awọn akọni n ko lọ kuro ni Adamasingba loni nibi ayẹyẹ ayajọ ominira ni ipinlẹ Oyo
olopaa
Àkọlé àwòrán, Olori ile aṣofin ipinlẹ Oyo, Debo Ogundoyin ati Ṣina Olukolu, kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyon sọrọ, Kini ẹ ro pe wọn n sọ?
ero
Àkọlé àwòrán, Lẹyin ti inu papa iṣere Adamasingba kún fọfọ tan, ẹsẹ ko gba ero nita Lekan Salami nitori kaluku wa woran ayẹyẹ ayajọ ominira Naijiria bi ijọba ipinlẹ Oyo ṣe n sami rẹ nilu Ibadan