Nigeria Tribunal: Ilé ẹjọ́ kéde Ganduje gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwéolúborí ninu ìdìbò sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano

Oríṣun àwòrán, @insightscoopng
Ile ẹjọ to n gbẹsun idibo ni ipinlẹ Kano ti ni Gomina Abdullahi Ganduje ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo Gomina to waye ni ipinlẹ naa.
Adajọ Halima Shamaki lo ṣe idajọ naa loni.
Aṣoju BBC to wa ni ile ẹjọ naa ni ẹsẹ ko gbero ni ile ẹjọ ọhun fun awọn to wa tẹti si ipẹjọ naa.
Bẹẹ naa ni awọn oloṣelu ko gbẹyin nibi idajọ ni bi wọn ṣe peju pesẹ si ile ẹjọ ọhun ni Kano.
Abba Yusuf lati abẹ asia ẹgbẹ PDP lo pe ẹjọ naa tako bi ajọ to n risi eto idibo ni Naijiria, INEC, ṣe kede gomina Abdullahi Ganduje gẹgẹ bi ẹni to pegede ninu idibo sipo to waye loṣu kẹta ọdun yii.
Ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii ni ajọ INEC kede pe idibo naa ko kẹsẹjari, to si kede idibo miran leyi ti Gandoje bori pẹlu ibo 1,033,695, ti Yusuf lati ẹgbẹ PDP si ni ibo 1,024,713.
Lẹyin eyii ni Yusuf kọ esi ibo naa to si gba ile ẹjọ lọ.
Nigeria Tribunal: Ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ yóò dajọ bóyá Ganduje àti Tambuwal yóò sì jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ wọ́n

Igbimọ igbẹjọ to n gbẹjọ idibo Gomina nipinlẹ Kano yoo fi idajọ le lẹ loni laarin Gomina Abdullahi Umar Ganduje ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ati akẹgbẹ rẹ Abba Kabir Yusuf ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party(PDP).
Bakan naa ni ile ẹjọ kun fọfọ ni ipinlẹ Sokoto nibi ti Gomina Aminu Waziri Tambuwal ti ẹgbẹ PDP naa n reti idajọ boya oun ni yoo yi jẹ Gomina tabi alatako rẹ Ahmed Aliyu ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC).
Adajọ Halima Shamaki ni yoo dajọ ẹjọ Ganduje ati akẹgbẹ rẹ ti wọn jijọ du ipo Gomina ninu idibo ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, 2019.
Ganduje ni ajọ el;eto idibo INEC kede pe o jawe olubori ninu idibo naa pẹlu ibo 35,637 nigba ti APC ti ri ibo 45,876 ti PDP si ri ibo 10,239.
Ti a ba pa ibo akọkọ ati ikeji ti awọn oludije naa ri gba, APC ri ibo 1,033,695 ti PDP si ri ibo 1,024,713.
Eyi tumọ si pe ibo 8,982 ni APC fi tayọ PDP.

Ajọ eleto idibo INEC kede nigba naa pe idibo naa ko kẹsẹ jari lo mu ki wọn tun ibo di.
Esi ibo atundi naa ni oludije PDP ni ko tẹ oun lọrun ti o si gbe ẹjọ naa lọ si iwaju igbimọ igbẹjọ idibo.

Kini o ṣẹlẹ ni Sokoto?
Ẹwẹ Gomina ipinlẹ Sokoto Aminu Waziri Tambuwal naa n koju itako lati ọdọ akẹgbẹ rẹ Ahmed Aliyu ti ẹgbẹ oṣelu PDP.
Tambuwal ti ẹgbẹ PDP gba ibo 512,002, eleyi to fi ju akẹgbẹ rẹ to gba ibo 511,660.

Oríṣun àwòrán, Tambuwal/Facebook
Aye ṣi wa fẹnikẹni lati tako esi idibo naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun.
O àti
Yóò dajọ bóyá àti yóò sì jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ wọ́n












