Kano Govnorship Re-run: Gómìnà Ganduje ní òun yóò fara mọ́bí èsì ìdìbò bá ṣe jẹ́

Governor Ganduje

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti sọ fun BBC pe oun yoo gba kadara ti oun ba fidirẹmi ninu atundi ibo gomina ti yoo waye jakejado ijọba ibilẹ mejidinlgbọn to wa nipinlẹ naa.

Ganduje fikun pe ẹru ko ba oun rara, nitori oun mọ pe ẹni to ba wu Ọlọrun l'oun gbe agbara fun.

"Idaniloju wa fun mi nipa atundi ibo yii nitori pe ati ṣe atunṣe si awọn aṣiṣe ti a ṣe lọsẹ meji sẹyin, ṣugbọn mo ti ṣetan lati gba kadara ti n ba kuna, maa si ki ẹni to ba jawe olubori ku oriire nitori mo gbagbọ pe ẹni ti Ọlọrun ba fẹ l'oun gbe agbara fun."

Bawo ni igbaradi ṣe n lọ fun atundi ibo naa?

Ajọ eleto idibo INEC nipinlẹ Kano sọ pe oun ti gbaradi fun atundi ibo naa.

Alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Shehu Risqua sọ fun awọn akọroyin pe ibudo idibo ọrinlerugba din ẹyọkan ni idibo naa yoo ti waye.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Shehu fikun pe awọn yoo pin awọn eroja idibo lọjọ Ẹti, ati wi pe awọn kọmisana ajọ INEC mẹta mi i lati ipinlẹ Ogun, Kebbi ati Zamfara yoo wa si ipinlẹ Kano lati ran an lọwọ̀ ninu iṣẹ naa.

Amọ ṣa, awọn kan to wa nilu Kano n binu pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fi atẹjade sita pe ko ni i si lilọ bibọ lati aago mẹfa idaji si mẹfa irọlẹ ọjọ Abamẹta.

Ireti awọn eniyan ni pe awọn agbegbe ti idibo yoo ti waye nikan lo yẹ ki wọn o ti pa iru aṣẹ bẹ.

Ipinlẹ Kano jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti atundi ibo gomina yoo ti waye lọjọ Abamẹta. Awọn ipinlẹ to ku ni Sokoto, Benue, Adamawa ati Plateau.