2019 election: Bí wọ́n ṣe ń ta káádì ìdìbò ní Kano

Sayen kuri'a laifi ne a dokar Najeriya

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ni ọjọ Abamẹta to jẹ ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ni ajọ eleto idibo INEC yoo ṣe eto ni awọn agbegbe kan ti wọn ti wọn ti fagile idibo ninu awọn ipilẹ kọkan ni orilẹede naa.

Ṣugbọn iṣoro kan ti wọn ti tu asiri rẹ lati ibẹrẹ ni bi wọn ṣe ń ṣe kara-kata lai bikita.

Ni waransesa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti sọ pe ọọ awọn ti ba ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ta ibo, wọn si sọ pe wọn n sa agbara wọn lati ri pe lati gbegidina iru iwa yii.

Sugbọn awọn akoroyin BBC, Yusuf Yakasai ati Halima Umar Saleh, ti wọn lọ si Kano lati gbe iroyin imurasilẹ fun idibo naa jade, ti ṣe iwadi lori bi wọn ṣe maa n ṣe owo kaadi ibo tita ati rira.

Iwadi wọn fi han pe awọn obirin ni wọn maa n fi ọrọ tita kaadi idibo lọ lọpọ igba.

Ati wi pe lọpọ igba wọn maa n lo ọgbọn ọtọtọ bii ọrọ awo ti yoo ṣoro lati mọ loju ẹsẹ nibi kara-kata kaadi idibo naa.

Osisẹ idibo kan nipinlẹ Kano

Oríṣun àwòrán, Getty Images

F'apejuwe , arabirin kan to kan si Halima Umar Saleh lati ta ibo rẹ , sọ fun Halima pe 'ó yẹ kí o ra àgé (Buta ni Hausa n pe age) nítorí kí wọ́n gbée lọ sí mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bíi sàárà'.

Lẹyin naa lo lo èdè buta tí Hausa n pe age to si sọ pe Buta n bẹ, buta (voter) si n bẹ.

Alaye fi han pe awọn agbofinro n wọ inu awọn adugbo ti wọn ti fẹ ṣe atundi-ibo yii lati gbegidina kaadi idibo tita.

Àkọlé fídíò, Demilade Adepegba: Mo má a ń gbàgbé fèrè ni, tí mo bá wà nílé ìwé

Ṣugbọn iru awọn eeyan yi ti wọn fẹ ta ibo wọn maa n ni ibi ti wọn ti maa n pade l'awọn adugbo kọkan, nitori ki ọwọ awọn agbofinro ma ba wọn nigba ti wọn fẹ ta ibo wọn..

Nigba idibo gomin ato kọja gan, awọn aworan ati fidio ti wọn s'afihan bi wọn ṣe lo owo nibi rira ibo n kakiri lori ẹrọ ayelujara.

Ileeṣẹ to n gbogun ti awọn to koba ọrọ aje Naijiria (EFCC) ati eyi to n gbogun ti iwa ibajẹ ( ICPC) wọn ṣe alaye pe ibo rira lodi si ofin ajẹbanu.

Ileeṣẹ ICPC sọ nibi apejọ ilaniloye kan ninu osu kejila ọdun 2018 pe ibo riria jẹ ijamba fun ilana democrasy.