Nigerian Celebrities: Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olórin, òsèré tó ti sàtìmọ̀lé rí!

Ẹ wo àkójọpọ̀ orúko àti àwòrán àwọn òsèré àti olórin lórílẹ̀-èdè Naijiria tí wọ́n ti sàtìmọ̀lélórí ẹ̀sùn kan àbí òmíràn.

Lola Margaret

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Lola Margeret to kopa ribiribi ninu ere ‘Bisola Aremu’ ni wọn fi panpẹ ọba mu ni orilẹ-ede Amerika wi pe o lu jibiti owo, amọ wọn fi i silẹ ni ọdun 2018, ti wọn si da a pada wa si Naijiria.
Dammy Krane

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé àwòrán, Dammy Krane ti orukọ rẹ n jẹ Johnson Oyindamola ni wọn mu lọdun 2017 fun ẹsun lilo ATM ti kii se ti e lati fi wọ ọkọ baalu. Wọn fi i silẹ lọdun kan naa. Osu Kesan, ọdun 2019 ni ileesẹ ọlọpaa ilu Eko mu u fun biba alaafia ilu jẹ. Wọn fi i silẹ lẹyin ti o san owo beeli rẹ, ti wọn si sun ẹjọ si Ọjọ Kọkanla, Osu Kewaa.
Yetunde Wunmi

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Gbajugbaja Osere tiata ti orukọ rẹ n jẹ Taiwo Akinwande, ti wọn n pe ni Yetunde Wunmi ni Ajọ NDLEA mu ni Osu Kẹwaa, ọdun 2006 fun ẹsun gbigbe oogun oloro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport (MMIA), Ikeja, ni ilu Eko. Ọdun mẹta lo fi lọ si ẹwọn lẹyin to jẹwọ pe lootọ ni oun gbe oogun oloro naa.
Godwon

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2009 ni wọn mu olorin takasufe,Neyu Godwin Nyan lori ẹsun pe o ja ile onile lorilẹede Amerika ti wọn si ti i mole fun ọdun mẹta titi di 2011.
Ibinabo Fiberesima

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Gbajugbaja osere Nollywood, Ibinabo Fiberesima ni wọn fi ẹsun ipaniyan kan lẹyin ti o wa ọkọ pa dokita kan ni ilu Eko ni ọdun 2006. Ọdun 2016 ni wọn gba beeli rẹ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun nitori wn ti gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ.
Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Azeez Adeshina Fashola ti wọn n pe ni Naira Mailey ni Ajọ EFCC mu lori ẹsun jija ole lori ẹrọ ayelujara. Amọ ninu fidio kan ni Naira Mailey ti sọ pe oti to igba 124 ti wọn ti fi panpẹ mu oun ni Ilẹ Gẹẹsi.
Rabi Ismaila

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan Rabi Ismaila ni ọdun 2002 nitori pe o pa ọrẹkunrin rẹ, to si sọ ọ sinu omi. O sa kuro ni ọgba ẹwọn ni ọdun 2011 lẹyin ti adajọ pasẹ fun pe ki wọn yẹ igi fun. Ọdun 2017 ni wọn sẹsẹ tun ri mu.
Sinzu

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Olorin takasufẹ Babalọla Falemi ti awọn eniyan mọ si Sinzu ni ijọba ilẹ Amerika ran lọ si ẹwọn dun meji lati ọdun 2016 si 2018 fun ẹsun ole jija, lẹyin to ji awọn kaadi ATM awọn eniyan, to si ji ọpọlọpọ owo ko to di wi pe ọwọ ba a.
Uche Odoputa

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Gbajugbaja osere Nollywood, Uche Odoputa ni wọn ka oogun oloro mọ lọwọ ni ọdun 2007, ti o si lo osu mẹjọ ni ọgba ẹwọn.

Àwọn àwòrán yìí wá láti ileesẹ Google ati Instagram