Ondo 2020: Afẹnifẹrẹ ní kí Tinubu sọ fún ẹgbẹ́ APC láti ṣe àmúṣẹ́ ilérí rẹ̀ fọ́mọ Nàíjíríà

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nibi iside ipolongo idibo gomina ipinlẹ Ondo lo ti pe fun atunto lori bi owo ṣe n wọle fun Naijiria labẹle.

Awọn asaaju kan ninu ẹgbẹ Afenifere ti bu ẹnu atẹ lu asaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lori bo se pe fun atunto ilana pinpin owo ajọni fawọn ipinlẹ ni Naijiria.

Awọn adari ẹgbẹ Afẹnifẹre to fi ero wọn han ni Oloye Ayọ Adebanjọ ati Yinka Odumakin, to jẹ akọwe ẹgbẹ naa.

Nibi ayẹyẹ iṣide ipolongo idibo APC nipinlẹ Ondo ni Tinubu ti pe fun atunto lori bi ijọba apapọ se n pin owo to n wọle labẹle nilẹ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu tun kesi awọn gomina nilẹ Yoruba lati ṣiṣẹ papọ, lori bi wọn yoo ṣe ma a ri owo labẹle ni agbegbe naa.

Tinubu ati Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Twitter

O fikun wi pe, ajọṣepọ laarin awọn gomina ni ilẹ Yoruba yoo sọ airiṣẹṣe awọn ọdọ ati iṣẹ, di ohun igbagbe ni ilẹ Yoruba.

Tinubu ni ti atunto ba de ba bi wọn se n pin owo to n wọle nilẹ yii, nipa ṣiṣe amulo awọn ohun alumọọni wa bo se yẹ, ọrọ aje wa yoo tubọ gbooro si.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Rotimi Akeredolu ni ipinlẹ Ondo n ri owo to to N600m si N700m pa wọle si ipinlẹ naa ni oṣooṣu.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Akeredolu fikun pe, ni 2018, awọn ri owo to to N1.5bn pa wole ni oṣooṣu.

Amọ, awọn adari ẹgbẹ Afenifẹre ni ki Tinubu ma fi ṣe ọrọ ẹnu nikan, ko bọ si gbagede lati beere fun atunto Naijiria, ki ohun ini ati bi owo ṣe n wọle labẹle ba le kaakiri ọpọlọpọ eniyan.

Wọn fikun pe, gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria ni wọn gbọdọ ma a pa owo wọle, paapaa awọn agbegbe to ni ohun alumọni to le mu ibugbooro ba bi owo ṣe n wọle ni abẹle.