Coronavirus:: Òògùn ìtura dé fún Covid-19! Ọ̀dọ̀ fásitì jànkàn Oxford ló ti jáde

Oríṣun àwòrán, Oxford University
Oogun arun Coronvirus kan ti wọn fiaridaju han pe o n ṣiṣẹ ti jade lati ile iwe giga fasiti Oxford eyi to si fi han pe ko mu ewu dani rara.
Bakan naa wọn jẹ ko di mimọ pe o maa n tọ agọ ara sọna nipa ohun to yẹ ko ṣe ki ara lee ji pepe.
- Kanye West ti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo àti díje dupò aàrẹ ilẹ̀ Amẹrika
- Ètò ìdìbò abẹ́lé sípò gómìnà APC ni ipinlẹ Ondo ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu
- Adelé Ọ̀gá Àgbà àjọ NDDC dákú rangbọndan lásìkò tí ìwádìí n lọ lórí ẹ̀sùn ìnákúnàá
- Wo bí Dorathy Bachor ṣe di gbajúmọ̀ lóríi Instagram lẹ́yìn tí ètò àgbéléwò BBNaija bẹ̀rẹ̀
Ayẹwo rẹ ti wọn ṣe lara eeyan ẹgbẹrun kan o le mẹtadinlọgọrin fi han pe abẹrẹ naa gbe awọn ajagun inu ara dide toloyinbo n pe ni 'antibodies' ati eroja ara mii fun ijagun (white blood cell) eyi to lee doju ija kọ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun to have iwadii yii jade ni Ireti gidi amọ ṣa, o ti ya ju lati mọ boya eyi nikan ti to lati dajọ pe o nṣiṣẹ lati da abo bo ara bẹẹ si ni awọn oogun ayẹwo mii ṣi wa lọna.
Orilẹede Amẹrika ti beere lati ra miliọnu lọna ọgọrun oogun naa bayii.
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
- Ó yẹ kí ìjọba gbé ilé ìwé tì pa títí di ọdún 2021- ASUU
- Akanbi mi, má fọ̀ ọ́, mo wà pẹ̀lú ẹ; ẹni tó ṣe ìgbéyàwó olórùka ló l'ọkọ- Lizzy Anjorin
- Afurasí tí Ọlọ́pàá ní ó pa Barakat, Grace àtàwọn míì l'Akinyele ti sọ̀rọ̀ pé...



















