Ron Jeremy: Òṣèré tó ti ṣe ''Blue film'' fún ọdún 40 ti wọ gàù pẹ̀lú ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja oṣere ''Blue Film'' Ron Jeremy tun ti wọ wahala sii lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ti fipa ba awọn obinrin to le ni mẹtala lọpọ, ti ọmọ ọdun marundinlogun si wa lara wọn.
Agbẹjọrọ ijọba ni ilu Los Angeles lo fi lede bẹẹ fun awọn oniroyin.
Awọn obinrin naa ni iṣẹlẹ naa waye ni ọdun 2004.
Amọ, lọwọlọwọ bayii, Jeremy n jẹjọ ẹsun ifipaba obinrin mẹrin mii lọpọ laarin ọdun 2014 si 2019.
- Olólùfẹ́ méjì jábọ́ láti àjà kẹsàn án lásìkò tí wọ́n n ṣe kerewà
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Akomolede: Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá
- Ìwọ tó ń ṣí ara sílẹ̀ lọ ṣọ́ọ̀ṣì, ṣé apàyàn kọ́ ni ẹ́ báyìí?- Mike Bamiloye
- Ọkùnrin kan da ṣọ́ọ̀ṣì rú lásìkò ìgbéyàwó, Ó ní òun lọkọ àárọ̀ ìyàwó tuntun
- Mi ò fẹ́ ìrànwọ́ ẹgbẹ́ òṣèré, àwọn kọ́ ló kóbá mi- Chief Kanran
Arakunrin Jeremy to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ti kopa ninu fiimu ibalopọ ta mọ si ''Blue film'' to ti le ni ẹgbẹrun ati ẹẹdẹgbẹrin (1700) lati igba to ti bẹrẹ ṣiṣẹ ere naa ni ogoji ọdun sẹyin.
Arakunrin Jeremy ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ronald Jeremy Hyatt foju bale ẹjọ ni Osu Kẹfa ọdun yii fun ẹsun ifipabanilopọ.
Awọn obinrin to fi ẹsun naa kan an jẹ ẹni ọdun marundinlọgbon, ọgbọn ọdun, mẹtalelọgbọn ati mẹrindinlaadọta ọdun.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Agbẹjọrọ fun Jeremy sọ wi pe ko jẹbi ẹsun kankan ti wọn fi kan an, ati wi pe awọn obinrin ni wọn ti ara mọ.
O fikun pe o ti le ni obinrin ẹgbẹrun mẹrin ti Jeremy ti balopọ, ti wọn si gbadun rẹ lai fi ẹsun ifipabanilopọ kan an.
Nibayii, Arakunrin Jeremy n koju ẹsun ifipabanilopọ ati fifi ọwọ kan ni lọna aitọ oniga-ogun laarin obinrin mẹtalelogun.
Mr Jeremy wo iwe Guiness Book of World Records gẹgẹ bi ọkunrin to kopa julọ ninu filmu to n safihan ibalopọ, iyẹn ''Blue Film'', ti wọn si ṣe fiimu Porn Star: The Legend of Ron Jeremy fun ni ọdun 2001 lati sọ itan aye rẹ.
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Ìpínlẹ̀ Osun kéde ọjọ́ táwọn iléèwé yóò ṣí padà
- YWC yọ Ààrẹ Banji Akintoye nípò àbi Akintoye tú ìgbìmọ̀ aláṣẹ YWC ká
- Wo àwọn orílẹ́-èdè mẹ́wàá tí kò ní coronavirus lágbàáyé, bá wo ni wọ́n ṣe ṣe é?
- Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
Bakan naa ni o ti kopa ninu fiimu Hollywood bii Moby, Guns N' Roses, Armin Van Buuren, LMFAO's Sexy ati I Know It.
Ti o ba jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an, yoo fi ẹwọn to to aadọrun ọdun jura.















