Davy dèrò ọ̀run nítorí 'Eré orí ẹní' ní ìlú Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idije talo mọ ere ori ẹni n ṣe ju ti ran arakunrin kan lọ sọrun apapandodo ni ilu Eko.
Arakunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Davy dagbere faye ni ile igbafẹ kan lagbegbe Ikọtun nilu Eko.
Gẹgẹ bi iroyin ti ṣe sọ, arakunrin yii gbe ọmọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Loveth lọ si ile igbafẹ naa lati lọ ree mọ ẹni ti o lẹmi ibalopọ julọ laarin awọn mejeeji ni akukọ ba fi kọ lẹyin ọmọkunrin rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iroyin fi idi rẹ mulẹ siwaju sii pe awọn mejeeji yii ti halẹ mọ ara wọn lori ẹni ti o lẹmi ere ori ẹni ṣiṣe julọ ni wọn fi fi ipade si ile igbafẹ naa lai mọ pe aṣe gbẹyin ori ẹni niyi fun arakunrin Davy.
Ẹgbẹrun lọna aadọta naira ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn sọ pe arakunrin naa gbe kalẹ pe bi ọmọbinrin naa ba lee gbẹyẹ mọ ohun lọwọ lori ẹni ohun yoo fun un ni owo naa.
Lẹyin ti Loveth gbọ ọrọ yii lo ti mura silẹ ti o si lọ duro de arakunrin naa ni ile igbafẹ ọhun.
Ọwọ keje ibalopọ wọn ni wọn n ṣe lọwọ ti arakunrin yii fi ṣubu lulẹ ti o si ku lori obinrin yii.
Eyi lo mu arabinrin yii fi igbe ta lati pe awọn alakoso ile igbafẹ naati wọn faa le awọn ọlọpaa lọwọ ti wọn si gbe oku arakunrin naa lọ si ile igbokupamọ si ni ile iwosan kan ti wọn ko darukọ rẹ.













