APC Ogun: Ẹjọ́ ti wà ní kóòtù, kò sẹ́ni tó lè tú ìgbìmọ̀

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ń se ipolongo ita gbangba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àjọ amusẹya ni ẹgbẹ oselu APC ti tu igbimọ ẹgbẹ ka ni ipinlẹ Ogun ati Imo gẹ́gẹ́bí àbájáde ìpàdé ẹgbẹ́ gbogboògbò.

Ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Ogun ti faake kọri wi pe ko si ẹni to le e tu igbimọ ẹgbẹ oselu APC ka ni ipinlẹ Ogun.

Ipinnu yii waye lẹyin ajọ amusẹya ni ẹgbẹ oselu APC pase lati tu igbimọ ẹgbẹ ka ni ipinlẹ Ogun ati Imo gẹgẹbi abajade ipade ẹgbẹ gbogbogbo.

Awọn adari ẹgbẹ oselu APC ni Ogun bu ẹnu atẹ lu asẹ yii, ati wi pe digbidigbi ni ẹgbẹ naa wa ni ipinlẹ naa, ti ko si si mimi kan to le yẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Wọn fikun wi pe ẹjo ẹni to jẹ adari ẹgbẹ ni ipinlẹ naa ti wa ni ile ẹjọ, ti ko si si asẹ ti o kọja ti ile ẹjọ lọwọlọwọ, nitorina asẹ ti ko lẹsẹ nilẹ ni asẹ ti ajọ amusẹya pa ni ipade to waye ni Abuja naa.

Ninu iwe ipejọ No CV/363/2018, ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Ogun ti rọ ile ẹjọ lati dẹkun igbimọ amusẹya ti APC lapaapọ lati le tu igbimọ abẹlẹ APC ni ipinlẹ Ogun.

APC Ilorin: Ilé -ẹjọ́ ní Balogun-Fulani ni alága APC

Ile ẹjọ ti fagile idibo to yan Rahman Rasaq gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara ati awọn ti wọn yan si ipo.

Ile ẹjọ ni Balogun-Fulani ni alaga ti wọn yan lọna to ba ofin mu.

Ile ẹjọ giga naa tun fagile gbogbo idibo abẹlẹ ti igun Bashir Bolarinwa se abojuto rẹ, ti ile ẹjọ naa si fagile igun naa wi pe alakalẹ rẹ ko ba ofin mu.

Ohun ti eyi tun mọ si ni pe ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara ko lee fa oludije miran kalẹ fun Ajo eleto idibo INEC yato si eleyiii ti igun Ishola Balogun-Fulani pa fa silẹ.

Idajọ ile ẹjọ giga naa tun ti mu ifasẹyin ba ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara ti o ti mẹhẹ, lẹyin ti Aarẹ Ile Igbimọ Asofin,Bukola Saraki ti kuro ni ẹgbẹ oselu APC naa ti o si fa ipinya laarin awọn ọmọ ẹgbeẹ ni ipinlẹ Kwara.

Ami idamọ APC

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ipinlẹ lo n koju aawọ abẹnu ninu ẹgbẹ APC lorilẹede Naijiria

Bakan naa, ajọ amusẹya ni ẹgbẹ oselu APC ti tu igbimọ ẹgbẹ ka ni ipinlẹ Ogun ati Imo.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ oselu APC fi lede, ti tu igbimọ naa jẹ abajade ipade ti ajọ amusẹya naa se ti Alaga ẹgbẹ, Adam Oshiomọle se adari fun ni ilu Abuja.

Àkọlé fídíò, Republic of Benin: ìtàn tó bí abẹ́sàn án kọjá bẹ́ẹ̀!

Igbimọ amusẹya naa ni yoo yan awọn igbimọ alabojuto ti yoo dele titi wọn yoo fi yan awọn alaga ẹgbẹ ni awọn ipinlẹ mejeeji.