Budget 2019: Buhari fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kúnwó owó tuntun òṣìsẹ́ sínú àbádòfin 2019

Oríṣun àwòrán, Christian C. Ozor
Aarẹ Muhammadu ti ni oun yoo gbe igbimọ kalẹ lori eto owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ to ba awọn aṣofin apapọ sọ nibi agbekalẹ aba eto iṣuna ọdun 2019 ni aarẹ Buhari ti kede eyi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ Buhari ni lootọ oun yoo ṣi gbe abadofin ranṣẹ sawọn aṣofin apapọ lori ilana owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ṣugbọn nitori ati yago fun wahala ti o lee fẹ waye lori ipese owo fun ilana owo oṣu tuntun naa ni oun fi tete fi sinu abadofin iṣuna ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
Wahala lori ilana owo oṣu tuntun yii ti gbode kan ninu ọdun 2018 pẹlu oniruru igbesẹ ati ijiroro laarin ijọba apapọ atawọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ki wọn to fẹnu ko si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bii owo oṣu oṣiẹ to kere julọ lorilẹede Naijiria.
O ni agbekalẹ igbimọ tẹẹkoto naa yoo wa lati wa ọna ti ẹkunwo oṣu tuntun naa yoo fi waye laisi pe awọn ẹka ijọba gbogbo n ti ọrun bọ oko gbese








