APC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'

Oríṣun àwòrán, @bolarinwa
Àwọn Fulani ṣe aṣemaṣe ninu ẹgbẹ APC ni- Kayọde Oyin Zubair.
Lana ni àwọn oloye ẹgbẹ APC ti Balogun-Fulani jẹ alaga rẹ ni ìpinlẹ Kwara ṣeto idibo abẹle wọn ni eyi ti wọn ni o lọ nirọwọrọsẹ, ti wọn si kéde Kayọde AbdulWahab Omotoṣẹ gẹgẹ bii oludije gomina fún APC nipinlẹ Kwara.
Lẹyin èyi ni ẹgbẹ APC lati òke fi atẹjade sita pé wọn ti túlé ká pé àwọn ọmọ oloye ẹka Balogun-Fulani kii ṣe oloye ẹgbẹ APC mọ, àti pe wọn kò láṣẹ lati ṣeto ìdìbò abẹle rara.
Nigba ti BBC Yorùbá kàn si ẹka àwọn Balogun-Fulani, o ni àwọn ni ilé ẹjọ gba wọle gẹ́gẹ́ bi oloye ẹgbẹ APC ni Kwara àti pé ẹni ti àwọn dibo yan ni INEC yóò gbà.
Kayọde Oyin Zubair ni Bashir Omolaja Bolarinwa ti ri ilana aatẹle fun aṣeyọri ìbò APC gbà láti Abuja ni eyi ti awọn yoo bẹrẹ ayẹwo loni ti idibo yoo bẹrẹ lọla.
O ní gbogbo wọọdu 193 to wa ni Kwara nidibo naa a ti waye.
Alaga igbimọ Ipolongo APC ni Kwara ni Oṣiọmọlẹ to jẹ olori ilé gan kò fọwọ si idibo ti àwọn Filani ṣe.