Nàíjíríà pé ọmọ ọdún 58 lónìí, ǹjẹ́ o mọ ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ orílẹ̀-èdè rẹ?
Lọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1960 ni Naijiria gba ominira kuro lọwọ ijọba ilẹ̀ Gẹẹsi.
Awọn baba nla wa bíi Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ (Yorùbá), Nnamdi Azikwe (Igbo), Alhaji Tafawa Balewa (Hausa) atawọn mii ni wọn jìjàngbara kí Naijiria tó bọ́ di olómìnira.
Pinpin sí ọ̀nà ìṣejọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ni a kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀. Ẹkùn Iwọ Ooorun, Ila Oorun ati Ariwa ni mẹta ti a kọkọ n lò.
Nigba ti o ya ni a bẹrẹ si ni lo àwọn ipinlẹ̀ kọọkan eyi ti ijọba n ṣafikun si titi to fi dori mẹrindinlogoji àti Abuja FCT ti a wà bayii.
Lọdun 1967 si ọdun 1970 ni Naijiria ja ogun abẹ́lé rẹ akọkọ ti ọpọlọpọ ẹ̀mí àti dukia lọ síi.