NLC: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ so ìyanṣẹ́lódì rọ̀

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ orílè-èdè Nàìjíríà ti so Ìyanṣẹ́lódì ti wọn gùn le rọ lọjọ Aiku.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ gba lati so iyanṣẹ́lódì naa rọ lẹyin ti ijọba apapọ kọ iwe ranṣẹ si wọn pe ohun ṣetan lati bẹrẹ ijiroro pẹlu ẹgbẹ naa lori ẹkun owo to kere julọ fun oṣiṣẹ.
Ijiroro naa yoo waye lọjọ kẹrin ati ọjọ karun un oṣu kẹwa.
Ṣáàjú ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà lawọ́n yóò gùnlé ìyànṣẹ́lódì tí kò ní gbèdéke ìgbà tí yóò parí pẹ̀lú bí wọ́n ti ṣe ti ẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan nàá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àfikún owó oṣù wọn.
Igun kejì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Trade Union Congress lo kọkọ kéde pé òwúrọ̀ ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn án ni ìyanṣẹ́lódì nàá yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọba apápọ̀ kùnà láti tún ìpáde ìjíròrò lórí ẹ̀kúnwó nàá ṣe ṣáàjú gbèdéke tí wọ́n fun un.

Ẹwẹ, akoroyin wa to wa ni ipinlẹ Rivers jabọ wi pe digbi ni wọn ti ile isẹ ijọba ati ile ise idajọ to fi mọ awọn ile ifowopamọ nilu naa.
Nilu Ilorin nise ni awọn ọmọ ẹgbẹ osise duro wamuwamu lati ri wi pe ko si ẹni to sisẹ lawọn ile isẹ ijọba ti wọn si rọ awọn osisẹ lati tele asẹ iyansẹlodi naa.


Akọ̀wé ẹgbẹ́ TUC, Musa-Lawal Ozigi, sọ fún BBC pé ọ̀sẹ̀ méjì ni àwọn fún ìjọba láti ṣe ìpàdé tí wọ́n dádúró.
Ó sọ pé ọdún 2017 ni ìjọba gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti jíròrò lórí owó oṣù tuntun tí àwọn òṣìṣẹ́ n bèérè fún. Ṣùgbọ́n, ó ku díẹ̀ kí iṣẹ́ parí ni Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́, Chris Ngige, dá gbogbo ètò dúró.
Ó ní ''ìrètí gbogbo òṣìṣẹ́ ni pé oṣù Kẹsàn án, ọdún 2018 ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ì gba owó oṣù tuntun, ṣùgbọ́n tí ìjọba kọ̀ láti ṣe àsẹparí iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ nàá. Èyí ló sì mú kí á pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì.

Oríṣun àwòrán, NLC
Ozigi ní ìgbà tí ìjọba bá tó ṣe ohun tó yẹ kó ṣe ni àwọn yóò tó fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì nàá.
Bákan nàá ló késí gbogbo aráàlú pé ''kí wọ́n ra oúnjẹ púpọ̀ sílé, àti pé kí ó yé wọn pé ìrọ̀rùn gbogbo ènìyàn ni ẹgbẹ́ TUC n jà fún.












