NJC: Ẹ̀sùn kíkéde ìyanṣẹ́lódì tí kò bófinmu ló mú kí a fòfinde adarí òṣìṣẹ́ méjì

Iwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, JNC ti buwọlu awọn mejeeji gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, JNC nipinlẹ Ekiti ti fofin de awọn meji kan ti wọn ti figbakanri jẹ adari fun ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ naa.

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, JNC nipinlẹ Ekiti ṣalaye pe idi ti wọn fi fofin de Ayọdeji Aluko ati Kọlawọle Ọlaiya ni pe wọn kede iyanṣẹlodi ti ko bofinmu pẹlu titu igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ati NLC nipinlẹ Ekiti ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdun mẹwa ni awọn mejeeji yii ko fi ni lee kopa ninu eto ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti.

Lọsẹ to kọja ni awọn mejeeji yii lewaju ifẹhonu han kan labẹ eyi ti wọn pe ni "Rescue team" ti wọn si bẹrẹ si nii le awọn oṣiṣẹ kuro ni ọfiisi wọn; ti wọn si tun kede iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ pẹlu ituka igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji to wa nipinlẹ naa.

Aṣia ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun mẹwa ni awọn mejeeji yii ko fi ni lee kopa ninu eto ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, JNC nilu Ado Ekiti, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC nibẹ, Ade Adesanmi pẹlu akẹgbẹ rẹ fun ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC Ọdun Adesoye ṣalaye pe Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, JNC ti buwọlu awọn mejeeji gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ oṣiṣẹ nibẹ atipe ofutufẹtẹ lawọn igbesẹ ti awọn mejeeji yii gbe.

Àkọlé fídíò, 'Ògidì ọmọ Yorùbá ni mí, kò sí ọ̀rọ̀ tí n kò lè túmọ̀'