Ọlọ́jọ́ Festival 2018: Àwọn tó n bọ Ṣàngó n jẹ iná níbi ọdún Ọlọ́jọ́
Ọdún Ọlọ́jọ́ ti ọdún 2018 gbàràdá nile Ifẹ.
Ọpọ ẹya ati oniruuru ede to peju sibẹ gba pe, kii se ilu Ile Ifẹ nikan lo yẹ ko maa se ọdun Ọlọjọ, gbogbo agbaye ni, nitori Ile Ifẹ ni ojumọ ti n mọ sile aye.
Ojọ kini, oṣu kẹwa, ọdun yii ni sisami ọdun Ọlọ́jọ́ yoo wa si ipari pẹlu aṣekagba ijo ibilẹ àti iṣafihan ohun eelo ọnà loriṣiiriṣii ni ilu Ile Ifẹ.
Ọdún Ọlọjọ ti 2018 ṣafihan pe Ṣango lọkọ Ọya titi lae.