Ọlọ́jọ́ Festival 2018: Ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́ ti Ilẹ Ifẹ̀ á parí pẹ̀lú àyájọ́ òmìnira Nàìjíríà

Ooni ti Ilẹ-Ifẹ, Alayeluwa Adeyeye Enitan Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Kabiesi, ki ade pẹ lori O

Ọjọ́ Iṣegun, ọjọ́ kejidinlogun, oṣu kẹsan an ni ayẹyẹ ọdun Ọlọ́jọ́ ti 2018 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ayẹyẹ àṣà Gbajure.

Ọdun Ọlọ́jọ́ ṣe pataki si gbogbo ọmọ Yorùbá paapaa àwọn to wa lati Ile Ifẹ to jẹ orisun.

Arole Oodua to jẹ Ọọni ti Ifẹ iyẹn Oba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II nipaseẹ ile iṣẹ aranilọwọ rẹ̀ ti kii ṣe tijọba, iyẹn, Hopes Alive Initiatives (HAI) ti nawọ iranlọwọ si awọn Aṣatipo ti ogun Boko Haram le nile ni agbegbe Wasa nilu Abuja.

Awon ti won fe gba vbọọlu

Oríṣun àwòrán, @Olafaremoses

Àkọlé àwòrán, Inu àwọn ọdọ dun nibudo Aṣatipo Wasa

Wọn pin ounjẹ loriṣiiriṣi, egbogi oyinbo, awọn irinṣẹ fun ọgbin ati awọn ohun eelo eré idalaraya bii àwọ̀n bọọlu alafẹsẹgba, aṣọ wiwọ fun ere idaraya fawọn aṣatipo nibudo naa.

Arabinrin Temitọpẹ Adeṣegun to jẹ igbakeji oludari ajọ HAI lo sọrọ fun Ọọnirisa to wọ ìléèdí ọlọjọ meje fun tọdun 2018.

O ni Ọba Ogunwusi nifẹ awọn aṣatipo naa ni ko ṣe ṣalai ranti wọn ninu ileedi to wa fun ayẹyẹ ọdun ọlọjọ lasiko yii. Bakan naa ni Asoya ti Ile Isoya, Oba Muraina Adedini mẹnuba awọn iṣe akanṣe ti Ọọni n ṣe fawon to ku diẹ kaato fun lawujọ.

Oba Muraina n gba bọọlu

Oríṣun àwòrán, @Olafaremoses

Àkọlé àwòrán, Ere idaraya ko yọ agba silẹ nibudo awọn Aṣatipo

Awọn ajọ aranilowo miran bii Development Support International(DSI) to jẹ awọn oniṣegun oyinbo naa wa si ibudo aṣatipo Wasa lati wa ṣeto ilera fawọn to wa ni ibudo naa.

Ọdún Ọlọ́jọ́ nile Ifẹ bẹ̀rẹ̀

Eto n lọ ni pẹruwu bẹẹni imurasilẹ ti lọ loriṣii fun ọdun Ọlọjọ eleyi ti Ọọ̀ni ti ilé Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjájá kejì yoo ṣe agbatẹru rẹ.

Ẹwẹ, Ọọ̀ni ti wọ 'léédì ọlọ́jọ́ méje láti ṣíde ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́ ti ọdun 2018.

Ọọ̀ni ti Ifẹ déjú mọ́lé fún ọjọ́ méje
Àkọlé àwòrán, Ọọ̀ni ti Ifẹ déjú mọ́lé fún ọjọ́ méje

Ìsélé yìí bẹ̀rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ àìkú lẹ́yìn tí ìrètí wà pé Ọọ̀ni tó jẹ́ àrólé Oduduwa yóò fara hàn ní gbangba pẹ̀lú adé ìṣẹ̀mbáyé tó jẹ́ wí pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló máa ń dé e.

Ìtàgé ti tò fún ọdún ọlọ́jọ́ 2018
Àkọlé àwòrán, Ìtàgé ti tò fún ọdún ọlọ́jọ́ 2018

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò, Iriwisi àwọn ará ìlú ṣe ọtọtọ lórí èsì ìdìbò Osun

Kó tó bẹ̀rẹ̀ ìsélé, Ọọ̀ni ti ṣe àbẹ̀wò sí ojúbọ 'Ilemọle' ní ìlú Moore láti ṣìpẹ̀ kò tó lọ ṣe 'ra rl mọ́lé níbi tí ojú òun àti ẹ̀dá alàyè kankan kò ní gáání ara wọn títí dí ọjọ́ ẹtì.

Ọba aládé yìí sọ pé òun yóò lo ọjọ́ méje yìí gẹ́gẹ́ bí ànfàní láti bá elédùmarè, àwọn irúmọlẹ̀ àtàwọn igba irúmọlẹ̀ sọ̀rọ̀ fún ìlú, ìpínlẹ̀ àti orílẹ̀èdè Nàìjíríà lápapọ̀ fún ìgbà ọ̀tun.

Ọọ̀ni ti Ifẹ déjú mọ́lé fún ọjọ́ méje

Oríṣun àwòrán, @Ọọniadimulaifẹ

Àkọlé àwòrán, Ọọ̀ni ti Ifẹ déjú mọ́lé fún ọjọ́ méje

Ọba Ogunwusi kí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọṣun kú oríire bí wọ́n ṣe hùwà dáradára sáájú, lákòókò àti lẹ́yìn ìdìbò tí wọ́n sì dúró lórí ṣíṣe ohun tó tọ́.

Ó kan sárá sí àwọn olùdìbò pàápàá àwọn ọ̀dọ́ pé wọn kò gbà kí wọ́n fi wọ́n ṣe jàndùkú sùgbọ́n tí wọ́n gba àláfíà láàyè lásìkò ìdìbò gómìnà tó kọjá.

Àkọlé fídíò, 'Lọ́gán tí mo bá di ààrẹ, mo máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́'