Osun Election Results 2018: Adeleke sọ pé PDP yóò gba ipò gómìnà rẹ̀ padà nílé ẹjọ́
Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun, Ademọla Adeleke, ti se apejuwe bo se fidi rẹmi ninu eto idibo gomina to sẹsẹ kọja naa gẹgẹ bii ifasẹyin ranpẹ, eyi ti yoo ni atunse laipẹ.
Ademọla Adeleke, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ to wa ni Ẹdẹ, tun fikun pe, ẹgbẹ oselu oun, PDP, yoo lo gbogbo agbara ofin to ba wa nikawọ rẹ lati gba ipo rẹ ti wọn ‘ji gbe’ pada.

O fikun pe "Ẹgbẹ oselu to n se ijọba lọwọ mọọmọ fi tipa-tipa gbe ifẹ ọkan wọn le awọn araalu lori ni, pẹlu bo se ko awọn janduku lati awọn ipinlẹ miran wa dunkoko mọ awọn araalu atawọn akọroyin."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adeleke wa rọ̀ awọn araalu lati bomi suuru mu, to si tun n fẹsun kan pe awọn janduku, to dibọn bii ologun pẹlu asọ sọja ati ọlọpaa, si wa yika ipinlẹ naa, ti wọn si lee lo anfaani ifẹhonu han lati pa awọn alaisẹ, ki wọn si tun se wọn lese pẹlu.
O wa fọwọ gbaya pe idagbasoke ipinlẹ Ọsun ati ti ẹgbẹ oselu PDP lo mumu laya oun.
Adeleke dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọsun
Olùdíje tó jáwé olúborí ṣùgbọ́n tí wọn kò kéde rẹ̀ nínú ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọṣun, Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke ti fi ẹ̀mí ìmore hàn sí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọṣun fún àtilẹ́yìn wọn.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí ó buwọ́lù lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹ́sàn án, Sẹ́nétọ̀ Adeleke ní àtìlẹ́yìn púpọ̀ tí òun rí jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀sun tún fún òun ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ síi.
Ó tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ará Ọṣun bu iyì kún òun ni tó fi jẹ́ pé òun ló jáwé olùborí nínú èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọṣun káàkiri àwọn ìjọba ìbílẹ̀.
"Mo fi ànfàní yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùdìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tó rí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó yẹ láti ní ìbò wọn. Bí ẹ ṣe dìbò yàn mí túnbọ̀ fún mi ní ẹ̀mí írẹ̀lẹ̀ síi ó sì tún fún mi ní ìgboyà láti sin àwọn aráàlú.
Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n lọ́ mọ mi lẹ́sẹ̀, ẹ ṣì dúró tì mí, ẹ dìbò fún mi bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ dúró gbọingbọin lórí ìpinu yín. Ẹ gbà mí gẹ́gẹ́ bí ni tó leè ṣe ìràpadà. Mi ò leè sọ bí ọpẹ́ mi ṣe pọ̀ tóo", ni Adeleke wí.
Ó ní "a ó dé ilẹ ìlérí. Ó bẹ̀rẹ̀ dáradára, ìyìn sí Ọlọrun wa sì ni yóò gbẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ jhẹ́ ká fi ara wa jín fún ìlàkàkà nítorí ẹ ti fi hàn pllú ìpinu yín. À lée fi tipátipá mú alágbára láti ṣe ifẹ́ aráàlú.
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín", Ló bá parí ọ̀rọ̀.
Ibùdó ìdìbò 7 ni yóò tún ìbò dì l'Ọṣun

Ẹ̀wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìdìbò ṣe sọ ọ́, wọ̀nyìí ni àwọn apa ibi tí wọn yóò ti tún ìbò dì ní ìpínlẹ̀ Ọṣun:
Orolu LGA
Ibùdó mẹ́ta ní ìjọba ìbílẹ̀ Orolu
Ifẹ South
Ibùdó méjì ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ South
Ifẹ North
Ibùdó kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ North
Oṣogbo LGA
Ibùdó kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Oṣogbo
Àfojúdi ló kóbá APC l'Ọṣun- Lai Mohammed.
Minisita fun ifitonileti ati Asa ni orilẹ-ede Naijiria, Lai Muhammed ni APC fi ọwọ yẹpẹrẹ mu PDP lori idibo Ọṣun ni won ko ṣe jawe olubori.
Lai Muhammed ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn maa lọ gbaradi fun awọn agbegbe ti wọn yoo ti lọ tun ibo naa di.

Amọ, Minisita naa fikun pe ẹru ko ba awọn latari idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun 2019Link.
Lai Mohammed ni àwọn faramọ igbẹ́sẹ̀ INEC ṣugbọn APC a tun ara mú láti rọ àwọn èèyàn Ọṣun sii.
O mẹnuba ẹ̀rí ti APC naa ni lori ìdìbò Ọṣun.
Ìdìbò Ọṣun
Nínú ìkéde àjọ INEC, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fi ìbò 254,698 gbà a mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wà lórí aléfà lọ́wọ́ tí wọ́n ní ìbò 254,345.
Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìbò méjèèjì ni 353. Gbogbo ìbò tí INEC fagilé ni 3,498.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Adeola Fiwapẹ tó jẹ adarí ètò ìdìbò náà kéde lórukọ INEC pé wọ́n yóò ṣe àtúndì ìbò àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan.
O ṣalaye ìdí ti èyí fi ri bẹẹ pe odiwọn ìbò ti awọn oludije mejeeji to ṣaaju ninu idije naa fi ju ara wọn lọ ko pọ to odiwọn iye ìbò ti wọn fagilé.
Fun idi èyi atundi ìbò ni yóò foju gomina tuntun fun ipìnlẹ Ọṣun hande.


















