OsunElectionResult2018: Báwọn kan se faramọ́ ìlànà ìdìbò náà, làwọn míì takòó

Eto idibo gomina nipinlẹ Ọsun ti waye, to si ti lọ bayii pẹlu atundi ibo to tẹle, eyi to wa sopin lọjọbọ.
Ninu esi ibo naa ni oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, Alahaji Adegboyega Oyetọla ti fi ẹyin alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke janlẹ pẹlu atundi ibo to waye naa.
Amọ onirruuru ero awọn ọmọ ilẹ yii lo se ọtọọtọ lori eto idibo naa, paapa nitori awọn ẹsun iwa jagidi-jagan, ọyaju, idunkooko mọni ati itabuku ẹni ti wọn lo waye lasiko atundi ibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lawọn oju opo ikansira ẹni bii Twitter ati Facebook, bawọn eeyan kan se n ki ajọ Inec atawọn agbofinro pe wọn fakọyọ, naa ni awọn eeyan kan n yọ suti ete si wọn.
Loju opo Twitter, @fkeyamo, to jẹ ti Festus Keyamo ni to ba jẹ pe lootọ ni eru ibo waye, esi ibo ti oludije APC ati PDP ni ko ni sunmọ ara wọn pẹki-pẹki, nse ni ẹni to ba fẹ se mago-mago ibo yoo yi ibo to pọ sọdọ ara rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Njoku Machi @MachiNjoku ni esi ibo gomina nipinlẹ Ọsun yii ni yoo sọ fun awujọ agbaye nipa eto iselu ijọba alagbada taa n se ni Nigeria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Kayọde Ogundamisi, @ogundamisi, lero tiẹ ni, to ba di igba miran, ẹlo ọpọ akoko si lati polongo ibo, se aato, dipo kẹ maa tan iroyin ti ko jẹ ojulowo kiri.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ben Murray Bruce, @benmurraybruce sọ ntiẹ wipe ole ojuaye lo waye nipinlẹ Ọsun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ajọ eleto idibo ilẹ wa, Inec wa n kọminu n tiẹ lori abajade eto itọpinpin atundi ibo Ọsun.
@inecnigeria, Inec ni o ya wọn lẹnu pe wọn mu awọn olutọpinpin ibo kan lawọn agọ idibo, tawọn yoo si sewadi rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Ileesẹ ọlọpa tako iwa ipa lasiko ibo
Wayi o, ileesẹ ọlọpa orilẹede Naijiria ti ṣe alaye ọrọ wipe ko ni si anfani fun ẹnikẹni lati tasẹ agẹrẹ si ofin ninu atundi ibo si ipo gomina ti yoo waye l'Ọjọbọ.Igbakeji ọga agba ajọ ọlọpa, Habila Joshak lo fi ọrọ naa lede l'Ọjọru nibi ipade awọn oniroyin to waye ni olu ile iṣẹ ajọ ọlọpa tokalẹ si ilu Ọṣogbo.O ni iroyin ti o n to ajọ naa lọwọ ni wipe awọn janduku kan ti n gbero lati da atundi ibo naa iru, sugbọn ẹnikẹni ti o ba da iru aṣọ bẹẹ ṣoro yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ sí:
Joshak fi kun ọrọ rẹ wipe ajọ naa yoo gbena woju ẹnikẹni ti o ba n fi ẹsẹ gbalẹ kiri lai ni ohunkohun ṣe ni awọn ibudo ti idibo yoo ti waye."Gẹgẹ bii ile iṣẹ agbofinro, ajọ ọlọpa ko ni fi aye gba ẹnikẹni lati tapa si ofin. Ao jọ gbena woju ara wa ni pẹlu ẹnikẹni ti o ba gbero lati da eto iṣejọba awara ru. Ajọ ọlọpa ko ni tẹti ninu ojuṣe rẹ lati ṣe afihan gbogbo awọn ọta ilọsiwaju. A keesi awọn oludibo lati pa ofin mọ, ki wọn si ṣe ojuṣe wọn lai si ibẹru."Igbakeji ọga gba ajọ ọlọpa fi kun ọrọ rẹ wipe aabo to peye wa fun gbogbo ẹni ti o ba pa ofin mọ ninu atundi ibo ti yoo waye lọjọbọ, pẹlu alaye wipe ajọ ọlọpa ati awọn ẹṣọ aabo to ku ni yoo jọ ṣiṣẹ pọ fun eto aabo to fi ẹsẹ mulẹ.
O tẹsiwaju wipe awọn oludibo to ni kaadi wọn lọwọ ati awọn oṣiṣẹ to n ṣe akoso eto idibo nikan ni yoo lanfani si awọn idubo ti atundi ibo yoo ti waye.

Oríṣun àwòrán, CDD
Joshak parọwa si awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati ma daṣọ ro ẹnikẹni ti o ba gbero lati ṣe ohun aito, boya nipa rira ibo ni, tabi ihuwa ipanle.
Dipo bẹẹ, o ni ki wọn kesi awọn agbofinro lọgan ti wọn ba ti kẹẹfin awọn aṣebaje. Atundi ibo si ipo gomina ipinlẹ Ọṣun yoo waye lọjọbọ ni awọn ibudo idibo meje to wa ni ijọba ibilẹ mẹrin ọtọọtọ ti awọn kudiẹkudiẹ ti waye lẹhin ibo ọjọ kejilelogun oṣu kẹẹsan ọdun yi.
Ijọba Ilẹ Gẹẹsi, orilẹede Amerika ati European Union ti rọ awọn oludibo Oṣun lati ri pe ko si jagidijagan, ẹru ati ibo rira ni atundi ibo ti yoo waye ni Ọjọbọ ọsẹ yii ni ibudo idibo meje ni Ipinlẹ Osun.
Awọn ileeṣẹ to n ṣoju ijọba Ilẹ Gẹẹsi, orilẹede Amerika ati European Union lo jumọ gbe atẹjade kan sita ni ọjọ Iṣẹgun ninu eyi ti wọn ti gboriyin fun awọn ara Osun fun didi ibo ni alaafia.
Wọn si tun gb'oṣuba fun ajọ INEC ati awọn oṣiṣẹ aabo, nitori pe idagbasoke ti ba bi wọn ṣe n ṣeto idibo.
Atẹjade naa sọ pe, "A n rọ gbogbo eniyan lati rii pe eto idibo naa pari ni irọwọ-rọsẹ, bi INEC ṣe n ṣeto lati ṣe atundi ni awọn ibudo idibo meje, nibi ti awọn kan ko ti raye dibo ni Satide to lọ bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ẹbi wọn.
"Ẹnikẹni to ba jawe olubori ni Ọjọbo gbọdọ ṣe oun to tọ, bẹẹ naa ni ẹni to ba fidi rẹ mi gbọdọ ṣe bi o ti tọ."