NigeriaIndependence2018: Aarẹ Buhari ni kí àwọn ènìyàn túbọ̀ ni sùúrù

Buhari
Àkọlé àwòrán, Buhari ṣeleri latifaaye gba alaafia ninu idibo 2019

Buhari fi dá àwọn ènìyàn Naijiria loju pe oun kò ni dẹkun láti mu idagbasoke to yẹ ba Naijiria.

Ni ṣoki aarẹ sọrọ lórí igbiyanju ijọba rẹ lati tun agbegbe Niger-Delta ṣe ati láti mu ìrètí àwọn ọ̀dọ́ ẹkùn náà ṣẹ.

O mẹnuba àwọn aṣeyọri bii ipese ounjẹ fawọn akẹkọọ ile iwe alakọbẹre ni eyi to ti n jẹ ki ọpọ ọmọ pọ sii nile iwe.

O sọrọ lori awọn iṣoro bii ti ayipada oju ọjọ ati eto ọrọ ajé ni eyi ti ijọba oun n sa ipá rẹ fún.

Buhari ni ìjọba oun mọ pe ọ̀dọ́ ni agbara orilẹ-ede fun idi eyi wọn ko kere lati dupo fun idagbasoke Naijiria.

Aarẹ gba àwọn eniyan nimọran lati gbe ni ìrẹ́pọ̀ ki wọn le jọ mu erongba Naijiria ṣẹ paapaa lori tiṣokan agbaye UN 2030 ati ti ilẹ Afrika ni 20160.

O ni igba gbogbo ni èrò awọn to lubgbadi ajalu Boko Haram maa n wa lọkan oun ti oun si n gbadura fun wọn pẹlu ileri pe ijọba oun kò ni faye gba awọn oniṣe ibi.

O gboriyin fawọn oṣiṣẹ eleto aabo pe wọn ku iṣẹ pẹlu ileri lati maa pese irin iṣẹ ti wọn ba nilo.

Ọdun 1999 ni Naijiria bẹ̀rẹ̀ ijọba alagbada ti a n lo lọ yii.

Ni ipari ọrọ rẹ, Buhari rọ àwọn eniyan Naijiria lati gba iṣọkan laye lai naani iyatọ ninu ìlú, ẹsin àti àṣà pẹlu ifidaniloju pe oun yoo tẹsiwaju ninu ohunkohun ti yoo mu alaafia ati ifọkanbalẹ jọba ni Naijiria.