APC Primaries: Àwa kò ṣiṣẹ́ fún Saraki rárá, A kò ni lọ darapọ mọ́ ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kankan

Àkọlé fídíò, APC Primaries: A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí

A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Lana ni àwọn oloye ẹgbẹ APC ti Balogun-Fulani jẹ alaga rẹ ni ìpinlẹ Kwara ṣeto idibo abẹle wọn ni eyi ti wọn ni o lọ nirọwọrọsẹ, ti wọn si kéde Kayọde AbdulWahab Omotoṣẹ gẹgẹ bii oludije gomina fún APC nipinlẹ Kwara.

Lẹyin èyi ni ẹgbẹ APC lati òke fi atẹjade sita pé wọn ti túlé ká pé àwọn ọmọ oloye ẹka Balogun-Fulani kii ṣe oloye ẹgbẹ APC mọ, Wọ́n yọ Balogun Fulani gẹ́gẹ́ bí alága APC àti pe wọn kò láṣẹ lati ṣeto ìdìbò abẹle rara.

Nigba ti BBC beere nipa èrè ti ẹka kọọkan fẹ ri gba ninu ìjà yii nitori pe, Yoruba ni a kii tile ẹjó de wa ṣọ̀rẹ́, Balogun-Fulani ni oun paapa fẹ ki ìjà naa pari lasiko yii, ki ikọ̀ mejeeji joko yanju ọrọ naa ki alaafia lè jọba ni Kwara ṣaaju ìdìbò 2019.

BBC Yorùbá fọrọ wa Kayọde Oyin Zubair to jẹ alaga igbimọ alukoro fun APC Kwara, to tun jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹka ti Omolaja Bolarinwa to jẹ alaga tuntun lẹnuwo.

O ni Ẹ̀ka Bọlarinwa-Àwọn Balogun-Fulani ń ṣiṣẹ́ fún Saraki ní ko si ẹlẹyamẹya ni APC Kwara nitori pe, awọn NWC lati Abuja ti tuleka ni eyi ti kò fun awọn Balogun-Fulani loore ọfẹ lati lọ ṣeto idibo rara.

Bakan naa lo fẹsun kan wọn pe Olori ilé igbimọ aṣofin agba, Bukọla Saraki ni àwọn Fulani n ṣiṣẹ fun kii ṣe APC rara.

Fulani ṣalaye fun BBC pe irọ ni ẹsun yii nitori pe lati igba ti Saraki ti ya kuro lọ PDP ni oun ko ti foju kan àti pe gbogbo ọrọ yii da lori èrò òkan Oloye Lai Mohammed to ni oun ro pe gbogbo àwọn maa tẹle Saraki ya lọ si PDP ni.

Kayọde Oyin Zubair ti awọn ẹka Bolarinwa ti wọn jẹ ti Lai Mohammed ni APC lati Abuja ti fun wọn laṣe lati ṣe idibo abẹlẹ ti wọn bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, 02/10/2018 àti pe awọn oludije mẹtala lo ti gba fọ'\omu lọdọ wọnẸ̀ka Bọlarinwa-Àwọn Balogun-Fulani ń ṣiṣẹ́ fún Saraki ní

Awọn agba ni o san ki alaafia tete jọba ko to di nla ti yoo maa gbẹbọ lọwọ ẹni.

Gbogbo ìgbìyànjú BBC láti ri Oloye Lai Mohammed to jẹ minista àṣà àti ifitonileti ni Naijiria bá sọrọ lori ọrọ yii ja si pàbó titi ti a fi n gbé iroyin yii sita.