Kenya Covid-19 fund: Aàrẹ pàṣẹ pé kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó lu owó ìtọ́jú aláìsàn ní póńpó

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orile-ede Kenya, Uhuru Kenyatta ti paṣẹ ki ileeṣẹ eto ilera ṣe afihan gbogbo iwe to ni i ṣe pẹlu ohun ti wọn ra nipa kikoju ajakalẹ arun Covid-19 ni Kenya.
Aarẹ Uhuru Kenyatta gbe igbesẹ yi lẹyin ti ọrọ jẹyọ pe awọn alaṣẹ kan ji ọpọ miliọnu dọla to yẹ ki wọn fi ra nkan eelo itọju arun Covid-19.
Lara awọn iwe aṣẹ inawo to ni ki wọn gbe jade leleyi ti ileeṣẹ to n pese eelo itọju alaisan ni Kenya, Kenya Medical Supplies Agency fi ra nkan.
Ileeṣẹ yi gan an ni wọn ni magomago ti waye nipa owo to yẹ ki wọn fi ra nkan eloo itọju alarun Covid-19.
Lasiko to n ba awọn Gomina ipinlẹ sọrọ ni Aarẹ Uhuru kede ọrọ yi.
Uhuru ni ''Ileeṣẹ ilera gbọdọ ṣe afihan ọna igbowojade ti ko lẹja n bakan ninu jade laarin ọgbọn ọjọ eyi ti gbogbo eeyan yoo ri loju opo ayelujara''
Awọn alaṣẹ ti wọn fi ẹsun yi kan sọ pe awọn ko mọwọ mẹsẹ.
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News.
- Ìpínlẹ̀ Osun kéde ọjọ́ táwọn iléèwé yóò ṣí padà
- YWC yọ Ààrẹ Banji Akintoye nípò àbi Akintoye tú ìgbìmọ̀ aláṣẹ YWC ká?
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo











