Corruption: Eni, eji, ẹta gómìnà tẹ̀lẹ̀rí tó ti ṣẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìkówó jẹ

Lánà òde yìí ní ilé ẹjọ́ tún fún gómìnà tẹ́lẹ̀ rí míràn ní ìdájo ẹwọ̀n ọdún mẹ́jila lóri ẹ̀sun oní kókó mọkandínlógójì fun ìkówójẹ lásìkò tó jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Abia.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria ló wá ń sọ pé ọ̀rọ̀ náà jọ bi ẹni pe ìpinnu ààrẹ Muhammadu Buhari láti fi ẹ̀yin gbogbo àwọn to n lu owó ìlú ni pónpo jalẹ kọja pé ọmọ ẹgbẹ́ ni ẹnikan tàbi alátako ni ẹnikeji.
Àwọn gomina àná mẹta to ti derò Ẹ̀wọn
1. Joshua Dariye (PDP) Gomina 1999-2007
Ní inú oṣù kọkanlá ọdun 2018 ní ilé ẹjọ to ga julọ wọ́n ẹ̀wọn ọdun mejila lẹ́yin to jẹ̀bi ẹ̀sun oníkókó mẹtadinlọ́gbọ̀n ti wọ́n si ni ko lọ ẹwọn ọdun mẹ́rìnla.
Joshua jẹ gomina ìpínlẹ̀ Plateau láti ọdun 1999 si ọdun 2007 to si tun di sẹnatọ tó ń sojú ẹkun gbùngbùn Plateau kí ilé ẹjoọ to dájọ pe ó jẹ̀bi ẹsùn ti àjọ EFCC fi kan.
Ẹsùn àkọkọ ní pé ó dá ìgbékẹ̀lé ti ará ìlú ni síi ti o si yẹ ko lkọ si ẹwọn ọdun mẹwàá nígba ti ẹsún keji niṣe pẹ̀lú owó kọngila fún atunse ayika mílíọnu kan lé ọwọ mẹfa (1.162bilion), eyi ni ẹwọn ọdun meji, sùgbọ́n mejeeji le lọ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ kòtẹmilọrun ni Ẹwọn ọdun mẹwàá ni o tọ si fún ẹsun
2. Jolly Iyame (PDP) Gomina 1999-2007
Ní ti Jolly Iyame ni tirẹ, ajọ EFCC gbe lọ si ilé ẹjọ ninu oṣù karunn ọdun 2018 lori ẹsun oni koko mọkanlélógójì fun dídari owo ilú to to bílíọnù kan ati ọwọ́ mẹ́fa (1.64bilion Naira) si akoto míràn láàrin ọdun mẹ́rin to fi jẹ gómínà.
Wọ́n ran lọ si ẹwọn ọdun mẹrinla lẹ̀yìn ti àwọn adájọ ẹlẹni mẹta èyi ti adajọ Abdul Aboki, pàdà wá dín ìdájọ rẹ̀ kù sí ọdun mejila.
Lẹ̀yìn èyí ni wọ́n ni ki Iyame san ẹẹdẹ́gbẹ̀ta din diẹ̀ mílíọnu naira gẹ́gẹ́ bi owó ìtanran botilẹ jẹ́ pé ẹ̀wọ́n ọdun mẹrinla ni wọ́n kọ́kọ́ ni ki ó lọ.
Jolly Iyame jẹ gomina ìpínlẹ̀ taraba láti ọdun 1999 si ọdun 2007
3. Orji Uzor Kalu (APC) Gominna 1999-2007
Ní àná òde yìí ni ilé ẹjọ pàda ṣedájọ Orji Kalu lori ẹsun ìkowó jẹ ti wọ́n ti EFCC fi kan-an.
Gomina ìpínlẹ̀ Abia tẹlẹ̀ ri ni ilé ẹjọ ni ko lọ fi ẹ̀wọ́n ọdun mẹjila jura nibi ìdájọ ti Justice Mohmmmed Idris dari.
Ilé Iṣẹ Slok ni wọ́n fẹ̀sun kan pe òun lò láti ko òwó àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Abia ni wọ́n ti gba fun ìjọba apapọ
Bakan náà ni wọ́n ko olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ Jones Ude ti wọ́n jo ń lu owó ìlú ní pònpò to si duro bi alaboju to owó lati lọ sẹ́wọ̀n ọdun marun.
Kalu lú o'wo ilú to lé ni bílíọnu maje naira (7.2bilion) ni ponpo.












