Golden passport: Kí ni ìdí tí àwọn olówó fi ń wá ìwé ìrìnà Malta?

Awọn aṣoju ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu n ṣe abẹwo si orilẹede Malta lati ṣewadi ibọwo fun ofin awarawa, bi itesiwaju ṣe n lọ lori iwadi si iku akọroyin lorilẹede naa.
Iku Daphne Caruana Galizia ni ọdun 2017 mi iṣejọba ati oṣelu orilẹede naa ti o si tun pe akiyesi si iwa ajẹbanu ati eto idajọ to mẹhẹ ni ilu naa.
Tita iwe eto irinna ''paali goolu'' ti di okowo goboi fun awọn olowo agbaye to wa ilu ti owo ori ti fuyẹ, eto ẹko to peye tabi orilẹede tuntun lati gbe paapaa fun ọrọ oṣelu.
Ṣugbọn elo gaan lo ba de lati jẹ ọmọ orilẹede Malta, ati ki la mọ nipa awọn to n ra iwe irina ilu naa?
If you bring €900,000, you can buy a Maltese passport and then you become an EU citizen."
Elo lo ma na lati di ọmọ orilẹede Malta?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba kede eto yi ni ọdun 2014 lati fa oju awọn olowo mora fun idokowo ati ọrọ aje. Lati ni iwe igbelu Malta, o ni lati da:
- €650,000 (£554,000) to jẹ owo idagbasoke ilu
- €150,000 si ọja idokowo ilu
- Ra ile ti owo re to €350,000 (tabi ki o yalegbe fun €16,000 lọdọọdun)
Apapọ gbogbo owo yi yoo jẹ́ €1,150,000, eyi to ju €900,000 ti aṣofin orilẹede Netherlands Sophie in't Veld kede.
Awọn to ba n fẹ lati di ọmọ orilẹede Malta tun ni lati gbe ilu naa ju odun kan lọ, ṣugbọn wọn ko ni lati gbe ilu naa ni dandan laarin asiko naa.
O ti to eeyan 833 to ti bẹrẹ idokowo pelu mọlẹbi 2,109 family to ti gba iwe ọmọ ilu lati igba ti eta naa ti bẹẹrẹ ni orilẹede Malta.
Iwe irina Malta fun eeyan ni anfani lati wọ awọn orilẹede miran ni Yuroopu nitori adehun Schengen.
Laarin ọdun 2017 si 2018, akojọpọ̀ owo ti wọn ti ri nidi eto naa jẹ €162,375,000 eyi to jẹ ida 1.38% ọrọ aje Malta laarin akoko naa, ṣugbọn ni 2018, adinku de ba rira iwe igbelu naa.
Ifanilojumọra gidi ni eyi jẹ fun awọn orilẹede kekeeke bi Malta lati mu idokowo wọ ilu wọn.
Ta lo n ra iwe igbelu Malta gan?
Ijọba Malta kii ṣe afihan apejuwe orilẹede tabi ẹnikẹni to n ra ''paali goolu'' yi amọ wọn ma fi iroyin sita ni ẹlẹkun jẹkun.
Yuroopu ni awọn to n kopa ninu eti yii ti wọpọ ju, leyin naa ni aarin gungbun Middle East ati Asia.
Amoṣa, awọn orilẹede ajọ isokan Yuroopu lẹto lati fi atẹjade sita lori iye awọn to di ọmọ ilu laarin ọdun kaakan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Leyin ti wọn bẹẹrẹ eto yii ni orilẹede Malta ni 2014, iye awọn to kopa lati orilẹede Saudi Arabia, Russia ati China pọ si.
Fun apẹẹrẹ, ni Saudi Arabia ko si ẹni to kopa lati Saudi Arabia ṣaaju 2015, ṣugbọn leyin igba naa, wọn le ni 400 to ti kopa.
Ko si ohun to ni ki eeyan ma ni iwe irinna ilu mẹji labẹ ofin, amọṣa wọn n fi ẹsun kan orilẹede Malta pe ọrọ ayederu ti n wọ eto naa.
Ajọ iṣoọkan ilẹ Yuroopu gbe iwe kan jade ni oṣu kini, ọdun 2019, eyi to wi pe wọn fura si eto Malta naa nitori o rọrun gidi ju awọn orilẹede iyoku ni Yuroopu.
Fun apọẹẹrẹ, ko jẹ dandan fun awọn to fẹ kopa ninu eto yi lati nile tabi ajoṣe kankan pẹlu orilẹede naa.
Ajọ ''Organisation for Economic Co-operation and Development (OECD)'' gbe atẹjade kan sita lọdun 2018, eyi to tabuku Malta gẹgẹ bii ilu ti eeyan le sapamọ si lai sanwo ori.
Ijọba Malta ni awọn maa n ṣe iwadi gbogbo awọn oloṣelu to ba fẹkopa ninu eto naa.
Ogbẹni van der Baaren wi pe ọpọlọpọ idile lo ma n fi eto yii ran awọn ọmọ wọn nile iwe loke okun, to si rọrun fun wọn lati kuro ni ilu orisun wọn.
Ni Yuroopu, Cyprus ati Bulgaria ni iru eto yii.
Laarin ọdun 2008 ati 2018, Cyprus fun oludokowo 1,685 ni iwe ilu, pẹlu mọlẹbi 1,651. Botilẹ jẹ̀ wi pe ni oṣu kokanla ọdun naa, eni 26 ni ijọba gba "paali goolu" nitori aṣiṣe.













