Yollywood Yemi Shodimu sọ̀rọ̀ pé àṣìlò ẹ̀bùn kò jẹ́ kí Nàìjíríà dàgbà sókè mọ́

Aworan Yemi Shodimu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Yemi Shodimu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Odu ni o jẹ lagbo oṣere tiata ni Naijiria kii ṣe aimọ f'oloko.

Bi eeyan ba ti wo awọn ere ileeṣẹ sinima Mainframe ni nkan bi ọdun meloo kan sẹyin, yo ranti arakunrin kan to kopa ribiribi ninu awọn ere ti Tunde Kelani dari wọnyi.

Yemi Shodimu lẹni taa n wi to si kopa ninu awọn ere sinima bi Ò le kù (1997), Ti oluwa ni ile (1993) ati Kòseégbé (1995).

BBC News Yoruba gba lalejo loju opo Facebook Live ti o si yanana ọrọ lori awọn ohun to ni ṣe pẹlu ere sinima ni Naijiria.

Diẹ lara awọn ohun t ri fayọ ninu ifọrọwerọ naa ree:

Ifarada pọ fawa oṣere nigba ta fi n kopa ninu ere sinima yatọ si tode oni

Gẹgẹ bi agba ọjẹ oṣere sinima yi ti ṣe ṣalaye, o ni tifẹtifẹ, tọkantọkan lawọn fi n se ere sinima lasiko tawọn.

O sọ pe awọn alakoso nigba naa ki ṣe alayaba.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

''Inu ọkan wọn ni itan ti wọn ba kọ ti maa n wa ati pe ẹkọ ti wọn kọ nipa gbigbe itan silẹ ni wọn n lo.''

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

bun pataki, ẹbun nlanla ni Tunde Kelani jẹ fun orileede Naijiria

Lori gbajugbaja oludari ere sinima yi, Yemi Shodimu ni o ṣeni laanu pe awọn to yabara ti wa pọ ninu ere sinima.

O ni ṣugbọn kii ṣe lagbo osere tiatia nikan ni wọn wa bii kii se pe wọn pọ ninu oṣelu ati awọn iṣẹ miran ni Naijiria.

Tunde Kelani

Ninu awọn nkan to sọnu ninu ere sinima ode oni, o sọ pe ti a baa n tiraka lati sọ itan oyinbo fun oyinbo, a ko le tẹsiwaju.

O ni aṣeyege pọ, kudiẹkudiẹ naa pọ to fi mọ awọn nkan aṣa wa to pọ ti a ko ti fi han fun araye ninu sinima.

''Ohun to n ṣe oyinbo loyinbo n kojọ ninu fiimu, ki lo de ti a wa naa ko gbe tiwa jade faraye gbọ?

O tẹsiwaju pe ''A ko ti bọ kuro ninu a n fi owo kun owo epo, owo ina, ki laa jẹ, ki laa mu, awọn nkan to n jo wa bi ina labẹ aṣọ pọ ti a gbọdọ fi han agbaye.''

Àkọlé fídíò, Tunde Kelani; Èmi ò jẹ́ Baba Wande ní owó lórí fíímù Tolúwanilẹ̀

Nipa isọkan Yoruba ati ọrọ iṣelu:

Sodiumu ni Yoruba ni lati pawọpọ ti wọn ba fẹ jana.

Shodimu yabara labẹ akori ọrọ yi lati sọ nipa oselu to n lọ lọwọ ni Naijiria

O sọ pe awọn to dantọ lati se oselu pọ ni Naijiria,bẹẹ lawọn ti ko yẹ ki wọn sunmọ oṣelu naa wa nibẹ.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

O wa fi kun pe abaabọ fifi awọn ti ko yẹ sipo ni Naijiria n ba finra bayi.

''A feran lati maa ṣadura lori gbogbo nkan ni Naijiria ṣugbọn ọlọrun ma jẹ ki ọrọ wa ṣu Ọlọrun.

Asilo ẹbun wa ninu nkan to n ṣe wa ni Naijiria ti a ko fi dagbasoke''