Tọkọtaya wọ “jẹsí” Messi àti Mbappe lọ́jọ́ ìgbéyàwó

Tọkọtaya tó wọ jẹsí Mbappe àti Messi lọ́jọ́ ìgbéyàwó

Oríṣun àwòrán, ARUN CHADRABOSE

Onírúurú àrà ni àwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá máa ń dá tí ọ̀rọ̀ bá di ti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ràn pàápàá lágbo eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò kí ń lè pa ìdúnnú wọn mọ́ra nígbà tí ọ̀rọ̀ eré bọ́ọ̀lù bá dá lórí agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n bá fẹ́ràn jùlọ.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kerala, níbi tí àwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pọ̀ sí jùlọ ní orílẹ̀ èdè India.

Ní India, eré ìdárayá Cricket ló gbajúmọ̀ jùlọ, tí àwọn ibẹ̀ sì máa ń ṣe àtìlẹyìn fún àmọ́ àrà ọ̀tọ̀ ni ìfẹ́ tí àwọn ará ìpínlẹ̀ yìí ní sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 tí àṣekágbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé wáyé láàárín orílẹ̀ èdè Argentina àti France, àwọn ará ìpínlẹ̀ náà gbáradì láti wo ìdíje náà dáradára.

Àmọ́ ohun kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni tí àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ àṣekágbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé yìí.

Bí ìmọ̀ àwọn tọkọtaya náà ṣe jọ lórí gbogbo nǹkan tí wọ́n máa lò ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, ó dàbí wí pé ẹnu wọn kò kò lórí orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọ máa ṣe àtìlẹyìn fún.

Sachin R tó jẹ́ ọkọ ìyàwó ló jẹ́ alátìlẹyìn Messi ti orílẹ̀ èdè Argentina nígbà tí ìyàwó rẹ̀ sì ń ṣe àtìlẹyìn fún orílẹ̀ èdè France láti gbégbá orókè níbi ìdíje náà.

Èyí ló mú àwọn tọkọtaya náà wọ “jẹsí” lórí aṣọ tí wọ́n fi ṣe ìgbéyàwó wọn níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà tó wáyé ní ìlú Kochi láti fi ìfẹ́ wọn sí eré ìdárayá náà hàn.

Athira tó jẹ́ ìyàwó wọ “jẹsí Mbappe láti fi ìfẹ́ rẹ̀ sí France hàn nígbà tí ọkọ rẹ̀ Sachin wọ “jẹsí” Messi láti ṣàtìlẹyìn fún Argentina.

Ìwé ìròyìn Malayala Manorama jábọ̀ pé ní kíákíá ni àwọn tọkọtaya náà kúrò níbi tí wẹ̀jẹwẹ̀mu ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ti ń wáyé láti lọ wó àṣekágbá eré bọ́ọ̀lù náà.

Ìpínlẹ̀ Kerala gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ ni ayẹyẹ lọ́kan-ò-jọ̀kan ṣì ń wáyé níbẹ̀ nítorí Messi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń ṣe àtìlẹyìn fún.