Ààlà ti fi oko ọ̀lẹ hàn, má da ẹ̀bi àìṣedéédé rẹ ru Ajimobi- Folarin sí Makinde

Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, @Folarin

Oludije ṣipo Gomina Ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, ninu eto idibo ọdun 2023, Senato Teslim Folarin, bu ẹnu atẹ lu Gomina Seyi Makinde lori ọna ti Seyi Makinde n gba ṣe ijọba nipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sọrọ ni Igboọra nibi ipade ẹgbẹ oṣelu APC ni agbegbe Ibarapa lo ti sọ bẹẹ.

Folarin so pe o han gbangba pe awọn ẹniyan Ibarapa ko tii ri atilẹyin ijọba ipinlẹ Ọyọ bo tile jẹ wi pe wọn fi ibo wọn gbe Gomina Seyi Makinde wọle ninu idibo ọdun 2019.

Folarin so eyi lati fesi si ọrọ ti Seyi Makinde sọ ní agbegbe Ibarapa laipẹ yii nibiti o ti fi ẹsun kan gomina ana Abiola Ajimobi pe owo ti o yẹ lati fi ṣe opopona ido si Ibarapa ni wọn lu ni ponpo.

Folarin ni nnkan buruku ni ki Ijọba to wa lori apeere da ẹbi aiṣedeede rẹ sori awọn ijọba tọ ti kọja.

O ni to ba jẹ wi pe loootọ ni ijọba Abiola Ajimobi na owo ijọba ipinlẹ Ọyọ laito o ye ki Seyi Makinde mu ẹri to daju lọ si ọdọ ajo ti o gbogunti iwa jegudujera fun iwadii.

O ni oun ṣetan lati mu ijọba ara ilu pada bo sipo,

Folarin ṣe ileri lati da ijọba pada si ọdọ awọn eniyan nigba ti wọn ba yan an ni afikun pe oun yoo mu ọpọlọpọ idoko-owo wa si agbegbe Ibarapa ati awọn agbegbe miiran ni ipinle Ọyọ.

Nigba ti o n sọ awọn iyatọ tu yoo mu wa si ipinlẹ Ọyọ àti agbegbe Ibarapa, Folarin ni asiko ti awọn agbẹ, oniṣe ọwọ àti gbogbo awọn ara ipinlẹ Ọyọ yoo rise ninu ijọba lodetan ti wọn baa ti diboyan gẹgẹbi gomina ipinlẹ Ọyọ. Oseleri lati mu adiku bàa awọn ti wọn tọrọ agbe lopopona ati lati ri wi pe awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ pada si ile iwe. Oni ilana isejọba ti oun a fi ṣe ijọba ipinlẹ Ọyọ lọna to dara ti wa nilẹ.