Ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lágbára látí tún Nàìjíríà ṣe tàbí kí ńkan tún bàjẹ́ síi– Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Others
Iyawo Gomin ana nipinlẹ Oyo, Oloye Florence Ajimobi, ni bakan meji ni eto idibo to n bọ lọdun 2023 yoo jẹ.
Aya oloogbe Abiola Ajimobi sọ pé o ṣeṣe ko gbe awọn eeyan Naijiria tabi ki ọrọ ba ibo miiran jẹyọ, eyi to le ba nnkan jẹ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
Nibo ni Florence Ajimobi ti sọ ọrọ yii?
Florence Ajimobi sọ eleyi nigba to n sọrọ nibi eto apero ti wọn fi ṣe ayẹyẹ ọjọbi ọkọ rẹ, Oloogbe Abiola Ajimobi ni fasiti ti ilu Ibadan lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.
O ni esi idibo ati nnkan to ba sẹlẹ lẹyin eto idibo ni yoo sọ bi ọjọ ọla orilẹede Naijiria yoo ṣe ri .
“A ti ṣe eto idibo abẹnu, a ti mọ awọn to n soju wa, sugbọn nibo ni a lọ lati ibi ti wa bayii.
“Nnkan ti mo mọ nipe eto idibo gbogbo lọdun 2023 le tun wa ṣe, bakan naa o le ba nnkan jẹ fun orilẹede Naijiria.”
Kini eto apero ọlọdọoọdun leyin iku Gomina Abiola Ajimobi je?
Florence Ajimobi ni eto apero ayẹyẹ ọjọbi ọlọdọdun ti awọn gbe kalẹ fun oloogbe Abiola Ajimobi ni awọn gbe kalẹ lati pe awọn oloye lorilẹede Naijiria lati sọ lori igbesẹ to le mu ilọsiwaju ba oriliẹede naa.
O tẹsiwaju pe bi eto idibo to n bọ nilo iriri lati ọdọ awọn adari to ti ṣe ijọba ri, awọn to ṣe lọwọ ati awọn ti ọjọ ọla lati yanayana ọna abayọ ti yoo sọ ayedẹrun fun awọn araalu.
Awọn wo lo wa sibi ayẹyẹ naa?
Lara awọn oloṣelu to wa ibi ayẹyẹ naa ni, Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin, Minisita fun ere daraya ati ọdọ, Sunday Dare, Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party, awọn Oba alaye ati awọn jankankan miiran lorilẹede Naijiria.
Gomina Ajimobi lo di oloogbe lẹyin to sa aarẹ lọdun 2020, to si fi Oloye Florence Ajimobi ati ọmọ marun-un silẹ saye lọ.















