Àwọn onímọ̀ Sáyẹ́nsì rí ojú ara tó ń mú ni gbádùn ìbálòpọ́ gan “Clitoris” lára abo Ejò

Ejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onimọ sayẹnsi ti ṣawari pe awọn ejo naa ni ibi oju ara obinrin to n maa n mu ara wa lọna fun ibalopọ eyi tawọn onimọ nipa ibalopọ maa n pe ni “Clitoris”.

Eleyi ti bu ẹnu atẹ lu igbagbọ ọlọjọ pipẹ ti awọn eeyan fi ro pe awọn ejo obinrin ko ni oju ara fun ibalopọ.

Akọsilẹ iwadii kan to jade l’Ọjọbọ ọsẹ lo ṣafihan aworan bi nnkan ibalopọ ejo obinrin ṣe ri gangan.

“Nnkan ọkunrin ejo”, “hemipenes” jẹ ohun wọn ti ṣe iwadii ijinlẹ nipa rẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Awọn mii wa bii pe o lẹ mọ ita ara bẹẹ si ni omii wa ninu ara.

Amọ oju ara ti ejo obinrin jẹ ohun ti awọn eeyan ti foju fo gẹgẹ bi awọn onimọ ijinlẹ ṣe sọ.

Ejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Kii ṣe ohun to pọn dandan pe o le lati ri - ṣugbọn awọn onimọ sayẹnsi ko kọbi ara si wiwa a.

“Fabu kan ti wa ri pe nnkan ọmọbinrin wa papọ ni, awọn onimọ sayẹnsi o rii nigba naa ti awọn eeyan naa si n ni igbagbọ pe ninu ki wọn maa fi oju ti ko tọ̀ wo ibalopọ awọ́n ejo. Eyi ni Megan Folwell, onimọ iwadii ijinlẹ sọ.

Iwe ti o pawọpọ kọ pẹlu eeyan kan eyi ti wọn ti ṣagbejade rẹ lori iwe iroyin atigbadegba “Royal Society B Journal” lọsẹ yii ri ibi oju ara fun igbadun ibalopọ nibi iru abo ejo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aṣewadii ni awọn nnkan to korajọ pọ ninu “cltoris” naa aọn bii ohun ti oloyinbo n pe ni “nerves, collagen ati red blood cells” eyi to n ṣiṣẹ ni mẹsan mẹwaa ki nnkan ibalopọ le maa dide.

Arabinrin folwell ni oun bẹrẹ si ni ṣe iwadii yii nitori itan ti oun ti ka nipa awọn oju ara ibalpọ Ejo – pe wn ko fi bẹẹ nii rara tabi o ti parẹ bi aye ṣe n yi si,” eyi ko kan ṣaa tẹ mi lọrun gẹgẹ bi ootọ,” o sọ bẹẹ.

“Mo mọ pe ọpọ̀lọpọ ẹranko lo ni “clitoris yii ko wa le mọgbọ́n wa pe ko si ninu gbogbo Ejo.”

O ni oun ṣaa ni oun gbudọ yẹ ẹ wo boya nnkan yii wa nibẹ abi Ọlọrun o da a mọ wọn.

O kọkọ bẹrẹ ayẹwo rẹ lori Ejo paramọlẹ to ti ku, o si ri “clitoris” – aworan ohun to ri bii ọkan to si tun rẹwa to rọra wa lẹgbẹ ẹya ara oloorun didun ti Ejo ma fi n fa oju ololufẹ mọra.

Ikọ̀ arabinrin yii ti wa gbe ayẹwo jade ti wọn ṣe lara oniruuru Ejo ti wọn fi abẹ la ẹda Ejo bii mẹsan to fi mọ Ọka “Carpet Python, Puff Adder ati Cantil Viper.” Wọn rii pe “clitoris wọn tobi ju ara wọn lọ́ o ṣugbọn gbogbo wọn da yatọ.

Titun itan ibalopọ laarin awọn Ejo kọ

Akọ ati abo Ejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo ohun ti awọn jọ fojusun wo papọ ninu igbeyawo awọn ni ko barawọn mu mọ, ti wọn ni lati tuka.

Iwadii ijinlẹ tuntun yii wa faaye gba afikun imọ ijinlẹ nipa ibalopọ laarin awọn Ejo eyi ti o le mẹnu ba igbadun ibalopọ fun abo Ejo.

Ṣaaju akoko yii, awọn onimọ sayẹnisi gbagbọ pe nipa ipa ni ibalopọ Ejo fi maa n waye ti akọ Eko yoo fipa lọ mọ abo Ejo lati baa lopọ̀,” Arabinrin Folwell sọ bẹẹ.

Eyi jẹ bẹẹ tori pe awọn akọ Ejo maa n fipa ṣe gbogbo nnkan lasiko ibalopọ nigba to jẹ pe awọ́n abo maa n farabalẹ.

“Ṣugbọn nisiyii ti a ti mọ pe “clitoris” wa lara abo Ejo, a lee maa boju wo itage, ara didide gẹgẹ ara ọna ti abo Ejo fi n nifẹ si ibalopọ pẹlu akọ.”

Bakan naa lo sọrọ nipa ere ifẹ ṣiṣe ṣaaju ibalopọ. Lọpọ igba, akọ Ejo maa n lọ mọ iru abo Ejo nibi ti “clitoris” wa.

“Ọpọlọpọ́ ihuwasi lo n fihan pe akọ wa nibẹ lati mu ki ara abo rẹ wa lọna fun ibalopọ́ ni.”

Onimọ ijinlẹ mii lori iwadii yii, Ọjọgbọn Kate Sanders ni Fasiti Adelaide sọ pe iwadii ọtun yii ko ba ma jẹ ṣiṣe bi kii ba ṣe ti Arabirin Folwell pẹlu ọgbọn ara ọtọ to mu jade.

“Iwadii tuntun yii fihan, idi ti Sayẹnsi ṣe nilo oniruuru eeyan to le ronu jinlẹ lati gbe ọpọlọpọ̀ ọgbọ́n atinuda jade fun ilọsiwaju.