Wó iye owó tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó bá gbà ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé yóò gba

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Orilẹede mejilelọgbọn lowa si idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Qatar lati koju arawọn fun ife to tobi julọ ni agbaye ninu ere bọọlu
Ko ki n ṣe iyi nikan lo wa nibi idije yii, ọpọlọpọ anfani lo tun wa nibẹ paapa owo ti onikaluku yoo ni anfani lati gba lẹyin idije naa.
Elo ni ẹgbẹ agbabọọlu to kopa idije ife ẹyẹ agbaye Qatar 2022 yoo gba?
Ẹgbẹ agbabọọlu to ba gba ife ẹyẹ agbaye yoo ni anfani lati gba owo to to milọnu mejilelogoji owo dọla. Owo yii lo le ni milọnu mẹrin si ti idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2018 lorilẹede Russia.
Afikun maa de ba owo ti ẹgbẹ agbabọọlu to gbe igba oroke lọdun ti idije ife ẹyẹ agbaye ba waye .
Wo bii wọn yoo ṣe pin owo fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu to kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Qatar
Ipo Owo ti wọn yoo gba (USD)
Ipo kini : $42m
Ipo keji: $30m
Ipo Keta $27m
Ipo kẹrin $25m
Ipele awọn mẹjọ (Quarter-final) $17m
Ipele oni mẹrindinlogun (last 16) $13m
Ipile ẹkun kọkan(Group stage) $9m








