Àfojúsùn èmi àti ọkọ mí kò papọ̀ mọ́ - Funke Akindele sọ̀rọ̀ lórí ìgbéyàwó rẹ̀ tó túká

Oríṣun àwòrán, others
Gbajugbaja oṣere tiata ati Igbakeji oludije sipo Gomina ipinlẹ Eko, Funke Akindele ti tu kẹkẹ ọrọ lori bii ipinya ṣe waye laarin oun ati ati ọkọ, Abdul Rasheed Bello, ti ọpọ mọ si JJC Skillz.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Legit, Funke ni afojusun oun ati ọkọ oun ana ni ko papọ mọ.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni gbogbo ohun ti awọn jọ fojusun wo papọ ninu igbeyawo awọn ni ko barawọn mu mọ, ti wọn ni lati tuka.
Ọ ni gbogbo igbinyanju lati jẹ pe igbeyawo naa si wa laye ni awọn gbe sugbọn ọrọ ba ibo miiran yọ, ti awọn si pinnu lati tuka.
“Otitọ ọrọ ibẹ nipe afojusun wa ninu igbeyawo wa ko paapọ mọ ati pe gbogbo igbinyanju lati ripe a si wa paapọ ni o jasi pabo. Fun idi eyi, ko si idi fun wa lati jọ wa paapọ.”
Bí ìgbèyàwó Funke Akindele ṣe túká rèé
Ọṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni ọmọ ọkọ Funke Akindele, JJC Skillz, Benito wa sori ẹrọ ayelujara lati sọ wi pe nkan ko rọgbọ ninu igbeyawo wọn.
Benito to jẹ ọmọ Mella, obinrin keji to bimọ fun JJC Skills sọ ninu fidio to ṣẹ nigba naa pe nkan ko lọ deede ninu igbeyawo naa.
Benito ni lẹyin ọdun meji ti oun gbe pẹlu wọn, Funke Akindele ki n ṣe ẹni ti eniyan ro pe o jẹ lawujọ nitori o buru jai.
Amọ JJC ninu idahun rẹ fi atilẹyin han fun iyawo rẹ to si kii ku akinkanju.















