Ẹ̀yin Abiyamọ, ẹ má sùn títí ìdájọ́ yóò fi wà lórí ikú àbúrò mi - Ẹ̀gbọ́n Bamise

Aworan

Awọn mọlẹbi Oluwabamise Ayanwola, to ku lasiko to wọ ọkọ BRT nilu Eko loṣu diẹ sẹyin seto isinku rẹ lọjọ Ẹti.

Ọjọ Kejilelogun Oṣu Keji ọdun 2022 ni ikede iku Bamise jade lẹyin to dede di awati ninu ọkọ BRT to wọ.

Awakọ BRT naa, tii se afurasi apaniyan lori iku Bamise, Andrew Nice Omininikoronwa, si ti n jẹjọ lọwọ́ lori isẹlẹ naa.

Awakọ naa to kọkọ dakẹ lẹyin iṣẹlẹ ọhun, lo tun sa lọ nigba ti ikede pe Bamise di awati tan ka ori ayelujara.

 Ẹwẹ, awọn agbofinro tọpasẹ rẹ, ti wọn si fa a le Ọlọpaa lọwọ fun iwadi.

Iroyin kan ni Awakọ naa kọkọ figba kan jẹwọ pe lootọ ni oun fipa ba Bamise lopọ, ti oun si fi silẹ nibi isẹlẹ naa.

Amọ nigba to ya, o bẹbẹ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọ́n fi kan oun.

Ọ̀rọ̀ iku Bamise yii lo gba ori ayelujara kan, ti gbogbo agbaye si ti mọ nipa rẹ.

Koda gbogbo ohun to rọ mọ iku rẹ ti wọ oju opo Wikipedia, nibi ti ẹnikẹni ti le ka nipa awọn eeyan tabi isẹlẹ pataki lagbaye.

Aworan

“Ìyàlẹ́nu ni pé ohun tí wọ́n sọ Bamise kù ni eléyìí lẹ́yìn àyẹ̀wò”

Ọkan lara awọn ẹgbọn Bamise to jẹ ọkunrin, Pelumi Abegunde, ṣalaye ohun ti oku Bamise la kọja lọwọ ayẹwo.

O ni o jẹ ohun iyanu ati eyi to ba ni lọ́kan jẹ gan ni pe lẹyin igba ti wọn ti ṣe awọn ayẹwo tan lara rẹ, wọn ti sọ oku rẹ di idakuda amọ́ inu oun dun pe o ṣiṣẹ akọ́ni ko to lọ.

“Gbogbo awọn ọmọ to n sọkun ni Bamise maa n ba ran aṣọ.”

O tọka si pe ọpọlọ́pọ́ awọ́n ọmọ́de ti wọn n sun ẹkun gidi gan, ti wọn to siwaju ọkọ to gbe posi oloogbe naa, ni Bamise maa n tọju wọn, to si maa n ṣe gbogbo wọn loore.

“Ofifo ti wọ́n fi silẹ niyii, o ni agbara gan, Ọlọrun Ọba nikan lo le fun wa ni ore ọfẹ lati gbe e kuro lara.”

O ni ninu nnkan ọgọ́run to yẹ ko jẹ ṣiṣe ni Bamise ti ṣe, ẹyọ kan to ku fun ijọba ni ki wọn ṣe lati jẹ ki idajọ ododo waye.

Pelumi Abegunde ni eyi ni ohun ti ẹbi n duro de.

Aworan

“Bamise jẹ́ ọmọ tó ń fi apá ṣiṣẹ́, kìí ṣe ẹni tó ń ṣe àgbèrè kiri”

Ọkan lara awọn ẹgbọn rẹ mii, Ayanwola Tayo naa ni “ki ijọba ba wa da gbogbo wọn lẹjọ ki wọn mu gbogbo ikoro ọkan ẹbi kuro.”

O ni tori iku Bamise mu ibanujẹ ati ikoro ọkan wọ inu ẹbi awọn to jẹ pe igba mii, inu igbe ati ibanujẹ lawọn maa n ji si.

O ni awọn ti padanu ọmọ to gba ẹkọ, to si ni iranti Bamise ko le lọ ninu ọkan awọn.

Ẹgbọn Bamise to jẹ obinrin, ẹni to ti fa irun ori rẹ dan kodoro lati kẹdun iku aburo rẹ, wa figbe bọ ẹnu, to si ni gbogbo ẹ ye Ọlọrun.

“Ọmọ onirinkurin ni wọ́n o ba pe, Bamise amọ Ọlọrun lo mọ nnkan to ṣe to si ni oun n rọ gbogbo Abiyamo lati ma sun titi idajọ yoo fi waye, ko ma baa si iru “Bamise” mii ti wọn yoo pa.

Aworan