Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Aje àti ọjọ́ Iṣẹgun tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi ọdún Keresimesi

Aworan

Oríṣun àwòrán, facebook.com/RaufAregbesola

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lati sami si ayẹyẹ ọdun Keresimesi.

Ijọba apapọ tu kede ọjọ Aje, ọjọ kẹji, oṣu Kinni, ọdun 2023 gẹgẹ ọjọ ọjọ isiinmi ayajọ ọdun tuntun.

Minisita ọrọ abẹle, ọgbẹni Rauf Aregbesola to fi ikede naa sita lorukọ ijọba apapọ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ku imura ọdun Keresimesi naa ati ayẹyẹ ọdun tuntun.

Aregbesola sọ fun awọn Kristẹni pe ki wọn maa wo awokọṣẹ Kristi ninu oun gbogbo ti wọn ba n ṣe.

O ni "O yẹ ki a maa wo awọkọṣe Jesu Kristi ninu iwa ati iṣẹ wa."

O fikun pe ibi ti alaafia ba n ti jọba ni eto ọrọ aje ibẹ yoo ma gboro. O wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijria lati lo asiko yii lati gba adura fun orilẹede Naijiria lati bori gbogbo idunkoko to n doju kọ lọwọ

Bakan naa ni Minista rọ awọn ọmọ Naijiria lati asiko yii ni oju ni alaakan fi n sọri , ki wọn si kesi ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ba kẹfin iwa ọdaran kankan lagbegbe wọn.