Iléepò, ṣọ́ọ̀bù àti ilégbèé jóná nínú ìjàmbá iná tó wáyé n‘Ibadan

Ọpọlọpọ dukia, to fi mọ awọn ibudo itaja, ile epo ati ilegbe lo jona di eeru lọjọbọ lagbegbe Apata niluu Ibadan.
Ni dede agogo mẹfa irọlẹ ọjọbọ, ọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ọdun 2022, ni isẹlẹ naa.
Nigba ti ileeṣẹ BBC News Yoruba kan si agbegbe naa lati se iwadi nipa ohun to fa idi isẹlẹ naa, awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn ba wa sọrọ.
Wọn salaye pe ọkọ agbepo bẹntiro to n bọ lati Odo-Ona, to n si morile ilu Abeokuta lo ṣadede sọ ijanu bireeki rẹ nu, to si bẹrẹ si ni kọlu awọn ọkọ yoku to n rin loju popo.
Lẹyin naa lo wa fi ẹgbẹ lelẹ nigba to de agbegbe Apata, eyi to fa ijamba ina ọhun.
Awọn eeyan agbegbe naa ni o pẹ diẹ ki ọkọ panapana ijọba to de sibi isẹlẹ naa sugbọn ileeṣẹ aladani kan pẹlu ọkọ omi rẹ ti kọkọ yọju sibi isẹlẹ naa lati paa ina ọhun.
"Ijọba ibilẹ ati apapọ, ẹ saanu awa onisowo to padanu dukia nibi ijamba ina yii"
Ọkan lara awọn to padanu dukia wọn, Ogbeni Akinloye Oloyo sọ fun BBC pe ẹgbẹlẹgbẹ dukia awọn onitaja to to aimọye bilọnu naira ni ijamba naa bajẹ.
O wa rawọ ẹbẹ sawọn ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ lati siju aanu wo awọn onisowo to padanu dukia wọn ninu ijamba ina naa.
Lara awọn eekan ijọba to yọju sibi isẹlẹ naa ni igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo, Amofin Bayo Lawal.
Awọn yoku ni Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin, Alhaji Sarafadeen Alli ati awọn eeyan jankanjakan miiran.















