2023: Màá pèsè iṣẹ́ tó tó 66,000 tí n bá di Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo – Adelabu

Oríṣun àwòrán, facebook.com/adelabu
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party, Oloye Adebayo Adelabu ti ṣe ileri lati pese isẹ to to ẹgbẹrun lọna mẹrindinlaadọrin to ba di gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2023.
O ṣo eleyi nigba to n kopa nibi ipade itagbangba kan pẹlu awọn oludije yooku niluu Ibadan, o ni laarin ọdun mẹrin ni oun yoo mu ileri oun wa si imusẹ.
Adelabu tẹsiwaju pe oun yoo rii pe oun pese isẹ ẹgbẹrun meji ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa ni ipinlẹ Oyo labẹ iṣe ijọba oun.
“Awọn isẹ wọnyi ni yoo wa fun gbogbo araalu, kaakiri gbogbo ipinlẹ Oyo: olukọ, awọn ẹsọ oju popo ati awọn mii.”
“Ijọba to wa lode yii ti kuna lati ṣe oun to tọ fun awọn araalu nitori rẹ ni nnkan ko fi lọ bo ṣe yẹ ko lọ.”
Bakan naa ni o ṣe ileri lati mu iyipada ba eto ọgbin ni ipinlẹ Oyo pẹlu awọn ohun elo oko igbalode ti yoo maa dojukọ awọn iṣoro ti awọn agbẹ ni ipinlẹ naa n koju.
O ni eyi yoo tun pese iṣẹ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ nipinlẹ Oyo.











