Orílẹ̀ èdè India fi ọmọ Nàìjíríà 198 ránṣẹ́ padà sílè, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede India ti fi awọn ọmọ Naijiria ti iye wọn fẹ ẹ wọ igba ransẹ pada sile nitori iru igbe aye ti wọn yan laayo ni orilẹ ede naa eyi ti ko tẹ ijọba India lọrun.
Ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹrindinlogun ni ajọ NEMA tẹwọgba awọn eeyan naa niluu Abuja.
Bashir Idris Graga, to jẹ agbẹnusọ NEMA sọ fun BBC pe ijọba India lo ransẹ si ijọba orilẹede Naijia lati wa ko awọn eeyan naa nitori awọn ko nifẹẹ si igbesi aye ti wọn n gbe.
Garga ni idi niyi ti ijọba Naijiria fi gbe igbeẹ lati ko awọn eniyan pada wa si orilẹ ede baba wọn.
“Awọn ọkunrin mejilelaadọjọ lo wa ninu awọn eniyan naa ti awọn obinrin si jẹ mẹrinlelogoji, pẹlu awọn ọmọde marun-un ti ọjọ oriwọn ko ju ọdun marun-un lọ.”
Bashir Garga tun ṣalaye pe awọn ṣe ayẹwo ilera awọn eeyan naa fun aisan kan ati omiran ni kete ti wọn ti balẹ si orilẹ ede yii.
O fi kun igbesẹ ṣiṣe ayẹwo ilera waye lari ri daju pe awọn eniyan naa ko ko aisan tabi aarun kan wọ aarin awọn eniyan orilẹ ede yii.
Bakan naa lo ni awọn fun onikaluku wọn ọgọrun dola lati wọ ọkọ lọ si ilu ati agbegbe ti awọn eniyan wọn wa.
O ṣalaye pe ọpọ awọn eniyan yii ni ko ni iwe igbeluu ni eyi to wa lara idi ti India fi tari awọn eniyan naa sile.
O ni pupọ awọn arinrinajo naa lo wa lati guusu orilẹede Naijiria, ti awọn diẹ si wa lati apa ariwa.
Garga tun fi kun pe ọpọ awọn miiran ni awọn ko i tii ri ko wa sile nitori gbese kan tabi omiran ti wọn jẹ ijọba India.
O ni ijọba India ko si ni fi aọn eniyan naa silẹ ayafi ti wọn ba san gbogbo owo ti wọn jẹ ijọba naa.















