Ayinla Omowura: Lateef Adedimeji, Mr Macaroni, Kunle Afolayan àtàwọn tó wà lórí ìtàgé eré náà sọ̀rọ̀ tó pọ̀

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Gbajugbaja olorin Apala nilẹ Yoruba ni Ayinla Omowura laye atijọ to si jẹ pe orin rẹ ko ṣi ṣee fọwọ rọ sẹyin titi di oni.

Bo tilẹ jẹ pe o ti faye silẹ lati nkan bii ogoji ọdun latari rogbodiyan kan to ṣẹlẹ nile ọti nibi ti ko le ṣai ma lọ, ko sẹnbi to mọ orin rẹ lati 1970s ti yoo gbagbe rẹ laelae koda, awọn ọdọ ti ko ba a laye gan ṣi tun n kan sara si orin rẹ.

Eyi lo mu ki gbajugbaja agba onkọwe ati oludari ere, Tunde Kelani tun orun rẹ sun to fi pinu lati gbe sinima Ayinla Omowura jade lọdun yii.

Kini awọn ọṣere naa sọ?

Tunde Kelani sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ pẹlu BBC Yoruba pe olorin pataki mẹta ni ọmọ ti ilu Abeokuta bi - Fela Anikulapo, Oloye Ebenezer Obe ati Ayinla Omowura to ni atapatadide ni ko to di ilumọọka tori orin rẹ.

Lateef Adedimeji ni Tunde Kelani lo gẹgẹ bii Ayinla gangan, apanilẹrin Debo Mr Macaroni ni alakoso eto gbogbo fun Ayinla ti Kunle Afolayan si jẹ Ajala Travel ninu sinima naa.

Awọn ọrọ ti wọn ba BBC Yoruba sọ ninu fidio bi wọn ṣe ya sinima naa wu ni lori jọjọ to si mu ko wu eeyan lati wo dandan.