INEC, kò sí ìdí kankan fún un yin láti má bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì ètò ìdìbò báyìí- Buhari

Aworan Aarẹ Muhammadu Buahri

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọkan lara ohun to jẹ pataki si oun ni lati pese eto idibo ti yoo waye lai si rogbodiyan tabi ko ni ọwọ mago mago ninu, ti esi idibo yoo si jẹ itẹwọgba fun awọn oludije.

Aarẹ gba ẹnu agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu sọrọ ninu atẹjade kan to fi ransẹ si awọn akọroyin.

Ninu ọrọ ti aarẹ sọ niluu Amẹrika, ti akọle rẹ jẹ “Ifọrọwerọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buahri ti orilẹede Naijiria.”

“INEC ti ṣetan nitori mo mu lọkunkundun lati pese gbogbo ohun ti wọn bere fun, ti a si ri pe a pese rẹ nitori n ko fẹ gbọ pe ijọba ko pese owo fun wọn.”

“Lati ọdun 2015 ni a ti ṣe atunṣe si awọn eto idibo wa, to si lọ ni irọwọrọsẹ.

Awọn eto idibo to ti waye fihan pe ibo awọn eeyan lo n sọrọ

Aarẹ Muhammadu Buahri tun si tẹsiwaju pe awọn eto idibo to ti waye sẹyin lorilẹede Naijiria ti fi han pe ijọba asiko nifẹ si eto idibo ti yoo lọ lia si rogbodiyan tabi ko ni ọwọ mago mago ninu.

“Eto idibo to waye 2019 ati awọn yooku nipinlẹ Edo, Osun, Ekiti, Anambra, ti fihan pe awọn araalu fi ibo sọrọ.

Eyi waye nitori a ti ṣe atunṣe si bi eto idibo wa yo ṣe waye.

“Lọdun 2012, nnkan ti a tun reti niyẹn, ki eto idibo lọ lia si rogbodiyan tabi wahala, eyi ti yoo fun awọn ajọ agbaye ni anfani lati fi wa ṣe awukọse ni lawujọ.”

Aworan apoti idibo

Oríṣun àwòrán, others

Eto idibo ọdun to n bọ yoo waye, awọn agbebọn kan n dunkooko lasan ni

Ọga agba fun ajọ INEC nipinlẹ Osun, Mutiu Agboke ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ko si ohun kohun ti yoo da eto idibo ti yoo waye lọdun to n bọ duro pẹlu bii awọn agbebọn ṣe n ṣe ikọlu si ẹka ati ayika ajọ ọhun.

O ni sọ eleyi ninu Osogbo nigba to n kopa ninu idanilẹkọ lori gbingba kaadi eto idibo saaju eto idibo ọdun to n bọ.

Agboke ni awọn ti pọkun eto abo ni gbogbo awọn ẹka ati ayika ajọ naa lati ripe ọwọ awọn agbebọn ko tẹ awọn ohun elo fun eto idibo.

O tẹsiwaju pe lilo kaadi dibo ati BVAS jẹ ilana ohun igbalode fun eto idibo ni o ti de lati mu irọnu ba eto idibo, ti ko si nkankan to le mu ajọ naa yaba kuro nibẹ.

Agboke wa rọ awọn orilẹede Naijiria lati yago fun tita kaadi idibo wọn nitori lo di si ofin orilẹede Naijiria, ti ijiya si wa fun pẹlu.