Àwọn kan ní Ayédèrú owó N1000 ti wà níta báyìí, wo bi ó ṣé lé dá ayédèrú rẹ̀ mọ

Oríṣun àwòrán, others
Opin oṣu to kọja ni Banki apapọ orilẹede Naijiria kede pe owo tuntun, N100, N200, N500 ati N1000 yoo jade fun lilo awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
Ọsẹ to kọja, ọjọ kẹdogun, oṣu kejila, ni owo ọhun jade fun lilo awọn araalu, ti ọpọ si ti bẹrẹ lati maa fi owo naa ṣe katakara wọn sugbọn o ṣe ni laanu pe awọn kan sọ pe ayederu awọn owo naa ti wa nita bayii.
Ọkunrin kan, to jẹ onisowo POS, to jẹ ọkan lara awọn to n sọ pe ayederu owo naa ti wa nita sọrọ ninu fọran to gbe sori ayelujara.
O ni onibara oun kan lo fun oun ni ẹgbẹrun kan to jẹ ayederu, eyi to nira fun oun lati damọ.
Ninu fọran ọhun, o salaye bii iyawo rẹ ṣe gba ẹgbẹrun kan to jẹ ayederu lọwọ onibara rẹ.
O ni nnkan ti oun fi mọ pe ayederu ni owo ọhun ni pe ami kan wa ti ajọ banki apapọ orilẹede Naijiria fi si awọn owo ọhun lara, eyi ti ko si lara ti ayederu rara.
Ami wura kan wa lara owo tuntun ti wọn ṣeṣe gbe jade ọhun, ti yoo si ni ra fun awọn to ṣe ayederu lati lo ami naa.

Oríṣun àwòrán, others
Wo ibi o ṣe le da owo gidi yatọ si ayederu
- Ami wura ti ajọ banki apapọ wa lara awọn owo naa. Owo ti ko ba ti ni ami wura yii, ayederu ni, ẹ sa fun.
- Ti ẹ ba gbe ina sunmọ awọn owo yii, ẹ ri ami ajọ banki apapọ naa ni bẹẹ, eyi to ko ni farahan ayafi ti ẹ ba gbe ina sunmọ
- Aworan to wa lara owo gidi farahan dada, ti ẹ ba gbe ina sunmọ tabi ti ẹ ba gbe ina kuro, o yoo ri aworan naa daradara sugbọn ọrọ ko ri bẹ ni bi ti ayederu nitori aworan to wa lara ayederu ma wo bakan ti wọn ba gbe ina sunmọ
- Ẹya beba ti wọn ṣe owo tuntun to jẹ gidi niyi lọwọ ju ti ayederu lọ. Ti beba ayederu si fẹlẹ lọwọ











