Àìsàn onígbáméjì “Cholera” bẹ́ sílẹ̀, ogún ènìyàn ti bá a lọ

Aworan omi ti ko dara àti cholera

Oríṣun àwòrán, WHO

Kò dín ní ogún ènìyàn tí wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí àìsàn onígbáméjì ṣe bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Cross Rivers.

Bákan náà ni àwọn ènìyàn ọgbọ̀n mìíràn tún wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú látàrí pé wọ́n lùgbàdì àrún náà.

Ìwádìí ikọ̀ ìròyìn BBC fi hàn pé omi tí àwọn ènìyàn náà ń lò ní ìlú wọn ni ó jọ wí pé kòkòrò tó ń fa àìsàn onígbáméjì ti kó wọ ibẹ̀.

Àwọn tó lu ìgbàdì àìsàn náà gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn ló jẹ́ àgbẹ̀ tí wọ́n ń lo omi kàǹga.

Akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Cross Rivers, Dókítà Iwara Iwara sọ fún BBC lọ́jọ́ Ajé pé ìtánkálẹ̀ àìsàn kọ́lẹ́rà náà tó tún ṣe àkóbá fún àwọn ọmọdé ṣekúpa ogún ènìyàn láàárín ọjọ́ méjì ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekureku.

Iwara ní ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti wá ti wá darí àwọn àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, àjọ Red Cross láti wá ojútùú sí àjàkálẹ̀ àìsàn náà.

Ó ní èyí fi hàn wí pé àwọn àgbẹ̀ tó wà ní agbègbè náà èyí tó pààlà pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Ebonyi nílò omi tó ṣe bùmu bùwẹ̀.

Ó fi kun pé ó hàn gbangba pé àwọn tó wà ní agbègbè náà kò ní omi tó ṣe é lò rárá .

Dókítà Janet Ekpeyong tó jẹ́ adarí àwọn il;e ìwòsàn ẹsẹ̀ kùkú ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò fún àwọn tó lùgbàdì àìsàn yìí.

Bákan náà ló ní àwọn tún ti ń fín gbogbo àyíká tí ìtànkálẹ̀ àìsàn náà ti ń wáyé.