Ọkọ mi ma ń fún mi lóògùn orun lálaalẹ́ kó tó fipá bá ọmọ tó ń gbé lọ́dọ̀ mi lòpọ̀ - Ìyàwó Doctor Olaleye

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ìyàwó dókítà Femi Olaleye tí wọ́n fẹ̀sùn kan wí pé ó fipá bá ìbátan ìyàwó rẹ̀ sùn ti sọ fún ilé ẹjọ́ pé ọkọ òun máa ń fún òun ní òògùn orun kó tó ṣe iṣẹ́ ibi náà.
Aderemi Faleye sọ fún ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀ àti ìfìyàjẹni tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 nígbà tí ìgbẹ́jọ́ wáyé bí òun ṣe máa ń sùn lọ fọnfọn láì ní mọ nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkọ òun báti lo oògùn oorun fún òun.
Ọkọ rẹ̀, Femi Olaleye ń kojú ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀.
Nínú oṣù kọkànlá ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko wọ́ Femi Olaleye lọ sílé ẹjọ́ wí pé ó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó jẹ́ ìbátan ìyàwó rẹ̀ lópọ̀ ní ilé wọn ní agbègbè Maryland.
Àmọ́ dókítà Olaleye ní òun kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.
Ilé ẹjọ́ fún dókítà ní ìdáǹdè àmọ́ kò ì tíì kúrò ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí kò ì tíì fi àwọn nǹkan tí ilé ẹjọ́ ń bèèrè kalẹ̀.
Aspirin àti Phenergan ni ọkọ mi fi máa ń fi kùn mí lórun
Aderemi Olaleye ní alaalẹ́ ni ọkọ òun máa ń fún òun ní oògùn tó pè ní “junior aspirin àti Phenergan”.
Ó ní òun kò mọ̀ wí pé àwọn oògùn tí ọkọ òun máa ń fún òun yìí jẹ oògùn láti jẹ́ kí òun sùn lọ láì ní mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé òun.
Ó ṣàlàyé pé tí òun bá ti sùn lọ tán ni ọkọ̀ òun máa ń yọ lọ sí yàrá ọmọ náà láti fipá ba lòpọ̀.
Ìyàwó dókítà náà ní ó jẹ́ ohun tó máa ń ba òun lọ́kàn jẹ́ tí òun bá rántí gbogbo àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà.
Ó ṣàlàyé pé nǹkan tí ọkọ òun máa ń sọ fún òun nígbà tó bá fún òun ní àwọn oògùn náà ni wí pé aspirin ma jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ òun ṣe dáradára pàápàá bó ṣe jẹ́ wí pé òun ti ń pé àádọ́ta ọdún lọ.
Aderemi Faleye fi kun pé ọkọ máa ń sọ fóun pé Phenergan máa jẹ́ kí ará òun balẹ̀ nítorí gbogbo wàhálà tí òun ń ṣe.
Ó ní òun kò mọ̀ wí pé irọ́ ni gbogbo ẹ àṣé ọkọ òun ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ kun òun ní orun ni.
Ó tẹ̀síwájú pé ilé ẹjọ́ le ṣe àyẹ̀wò ara òun láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni gbogbo nǹkan tí òun ń sọ.
Láti oṣù kẹta ọdún 2020 ni dókítà Olaleye ti ń fipá bá ọmọ náà lò pọ̀
Nígbà tí Aderemi Olaleye ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ agbẹjọrọ ìjọba nílé ẹjọ́, Babatunde Martins, ní ó pẹ́ kí òun tó mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé àwọn.
Ó ní oṣù kejìlá ọdún 2019 ni ọmọ náà ti ń gbé pẹ̀lú àwọn tí ọkọ òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ọmọ ọ̀hún lòpọ̀ nínú oṣù kẹta ọdún 2020.
Bákan náà ló fi kun pé yàtọ̀ sí pé ọkọ òun ń fipá bá ọmọ náà lò pọ̀ ní ṣe ló tún máa ń jẹ́ kó wo àwọn eré ìbálòpọ̀.
Aderemi ní ọmọ náà jẹ́wọ́ gbogbo nǹkan tí ọkọ òun ṣe fun un fún ẹ̀gbọ́n òun kan nígbà tí àṣìrì ọ̀rọ̀ náà tú sí òun lọ́wọ́.
Ìdí tí mo ṣe tú àṣírí ọkọ mi síta rèé
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí kò fi ṣe ọ̀rọ̀ náà ní òkú òru láàárín ẹbí, Olaleye ní òun náà bí ọmọ obìnrin tí òun kò sì gbàdúrà kí ẹnikẹ́ni ṣe ọmọ òun bí kò ṣe yẹ.
Ó ní nǹkan tí ọkọ òun ṣe kò dára rárá nítorí náà ni òun ṣe pariwo rẹ̀ fún aráyé.
Ó fi kun un pé tí òun bá dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, ọkọ òun ṣì máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹlòmíràn.
Aderemi Olaleye ní ẹni tó le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ẹni tó ń pè é ní bàbá, ó le fipá bá ọmọ tó bí nínú náà lò pọ̀.















