2023: Kò ni sí àyè fún fóònù lílò nínú ojúkòó ìdìbò, ìdí rèé – INEC

Idibo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria (INEC) ti tẹnumọ fifofin de lilo foonu alagbeka nibi ojuko idibo nigba ti gbogbo eniyan ba n kopa ninu eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ.

Alaga ajọ eleto idibo naa, Ọjọgbọ Mahmood Yakubu sọ eyi ni ọjọ Aje nibi ipade apero ajọ naa pẹlu awọn tọrọ kan nipa koko ọrọ ti wọn ṣepade le lori, “ipa ti owo n n ni lori idibo.”

Wọn n ṣe eyi ṣaaju idibo ọdun 2023.

Lara awọn to kopa nibi ipade apero naa ni aṣoju ajọ ọlọpaa, ti ajọ EFCC, ti ajọ ICPC, ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ, awọn ileeṣẹ iroyin, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba atawọn olugbaninimọran laarin awọn ẹgbẹ oṣelu (IPAC).

“Awọn araalu ko gbọdọ gba ki wọn fi owo tan wọn lati ra ibo wọn. Bakan naa, wọn gbudọ kopa gidi ninu fifopin si lilo owo lọna aitọ lasiko idibo nipa ki wọn maa fi ẹjọ iru nnkan bẹẹ sun ajọ INEC tabi awọn ajọ mii to lee kapa rẹ.

Idibo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lafikun, Awọn adari oṣiṣẹ alaabo gbudọ rii daju pe eyi jẹ koko iṣẹ ayẹwo wọn ṣaaju ati lasiko idibo.” Yakubu sọ bẹẹ.

Alaga ajọ INEC fi kun un pe ki awọn to maa n ni anfani lati ba araalu sọrọ ninu gbigbogun ti tita ati rira ibo, awọn bii: Ile ifowopamọ, awọn ile ijọsin, awọn adari ilu nigberiko, awọn oniroyin, ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ati paapaa julọ, awọn araalu.

“Ẹ jẹ ki n lo akoko yii lati fi ran gbogbo araalu leti pe ofin ti a gbe le lilo ẹrọ alagbeka foonu ni ojukoo idibo ṣi wa digbi.

Fun igba diẹ bayii, a ti ṣe atunto awọn ibudo idibo wa ki wọn baa le gbe apoti idibo sunmọ ẹgbẹ ojuko idibo lati mu ilana idibo ya ati lati ṣe idiwọ fun awọn karanbani oludibo kan ti yoo fẹ maa fi iwe idibo ti wọn tẹka si han awọn to fẹ ra ibo”.

Ki ni o le ṣe too ba ri eeyan to n da eto idibo ru ni ibudo rẹ?

“A n rọ awọn oludibo pe ki wọn ke si awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo nigbakuugba ti wọn ba rii pe awọn eeyan n ru awọn ofin to ṣe koko yii.”

O ni oun tun fẹ fi akoko naa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn ni ipinu lati rii pe ilana ṣiṣe eto idibo ati abajade eto idibo to yanranti lo waye ni Naijria. “A nigbagbọ pe gbogbo ọmọ Naijiria gan fẹ ka ṣe bẹẹ ,” Yakubu sọ eyi.

Yakubu wa fi da awọn araalu loju pe INEC yoo tẹsiwaju lati ṣe awọn igbesẹ ti yoo gbogun ti iwa tita ati rira ibo to si fi kun un pe awọn ni ifọkansin fun awọn araalu.

O ni INEC ti fẹ ṣe amulo awọn ohun elo imọ ẹrọ igbalode lati rii daju idibo ti ko ni si idiwọ lo waye lọdun 2023.

"Ohun ti awa ọlọpaa yoo ṣe lasiko idibo"

Igbakeji Ọga agba ọlọpaa, Bala Ciroma sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu ọpọlọpọ awọn to kopa ninu ibo rira to si tun fi kun un ọpọlọpọ tọọgi lawọn ti mu ti wọn n foju wina ofin nile ẹjọ bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọlọpaa yoo tun fi iṣẹ kun iṣẹ wọn lati rii daju pe awọn oloṣelu to maa n lọ kaakiri pẹlu ẹru owo nla nla lati fa oju awọn oludibo mọra yoo bọ si gbaga ọlọpaa.

Esi yii waye nigba ti aṣoju ẹgbẹ olugbaninimọran laarin awọn oloṣelu mẹnu ba ọrọ “ta ibo koo se’bẹ”.

Bakan naa ni ọga agba ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ ka abala ofin wọn to ni ṣe pẹlu idibo fun awọn oniroyin to si ki wọn nilọ lati ma jẹ ki awọn oloṣelu lo wọn. O tun ni ki awọn ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ rii pe wọn ni akọsilẹ awọn owo iṣẹ ti wọn ba gba lasiko idibo tori ile iṣẹ ti wọn ba gbamu pẹlu iwa to ru ofin alafia ilu ko ni lọ lai jẹ iya.