Russia/Ukraine war: Russia kó àwọn olórin sójú ogun láti ṣe kóríyá fáwọn ọmọ ogun

Aworan olorin Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orílẹ̀ èdè Russia ti kéde pé àwọn máa kó àwọn olórin lọ sí ojú ogun tó ń wáyé ní Ukraine láti fi ṣe kóríyá fún àwọn ọmọ ogun tó ń ja ogun náà.

Mínísítà fọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀ èdè Russia tó kéde àwọn oníṣẹ́ ọnà tí yóò máa kópa ní ojú ogun náà ní àwọn olórin àti àwọn tó máa ń fọn fèrè.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ológun UK fi síta ṣàlàyé pé Mínísítà fétò ààbò Russia, Sergei Shoigu ṣàbẹ̀wò sí Ukraine láti lọ wo bí àwọn ọmọ ogun tó wà lójú ogun.

Àmọ́ nínú àtẹ̀jáde tí ileeṣẹ́ ológun Russia fi sórí Telegram ní Shoigu kàn ṣe àbẹ̀wò sí àwọn agbègbè ibẹ̀ ni àti láti wo àwọn ikọ̀ ọmọ ogun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún gbé kalẹ̀.

Bákan náà ni àtẹ̀jáde ọ̀hún tún ní Shoigu tún bá àwọn ọmọ ogun tó ń ja ogun náà ṣùgbọ́n BBC kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni Shoigu ṣe àbẹ̀wò sí Ukraine fúnra rẹ̀.

Àtẹ̀jáde yìí lọ ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ológun UK ní ó dàbí wí pé ó ti ń rẹ ìjà àwọn ọmọ ogún Russia lórí ogun tí orílẹ̀ èdè ń gbé ti Ukraine.

UK tún fi kun pé ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn olórin wáyé lẹ́yìn tí wọ́n pàrọwà sí àwọn ará ìlú láti dáwó sí owó tí wọ́n fẹ́ fi ra èròjà orin fún àwọn ọmọ ogun náà láti lè fi ṣe kóríyá fún wọn.

Onírúurú awuyewuye ló ti ń lọ pé ó ṣeéṣe kí àwọn olórin náà máa ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ọmọ ogun tó wà lójú iná.

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn RBC ṣe sọ àwọn ikọ̀ olórin náà máa jẹ́ èyí tí ààrẹ Russia, Vladimir Putin máa gbà fúnra rẹ̀ àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olórin tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ọmọ ogun fúnra wọn.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ ogun Ukraine ní ogun ti ń le si ní agbègbè Bakhmut, ẹkùn ìlà oòrùn Donbas láti ọjọ́ Àbámẹ́ta.