Pásìtọ̀ kan, olùkọ́ kan àti àwọn mẹ́ta míì dèrò iléẹjọ torí wọ́n fipá bá ọmọ ọdún 11 lò pọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers ti gbẹ eeyan marun-un, ọkọ iya ọmọ naa, pasitọ kan ati olukọ ile-ẹkọ kan ṣiwaju kootu Majisireeti ti wọn jokoo ni Port Harcourt fun ẹsun pe wọn fipa ba ọmọbirin ẹni ọdun mọkanla kan lopo lọna aito.

Iwa aito naa lo wayeẹ niluu Buguma ni ijọba ibilẹ Asari Toru nipinlẹ Rivers.

Ninu iwe esun ti wọn fi kan wọn PMCNO/1771C/2022 awon ti won gbe ejo naa lo si ile ẹjọ ni Ebi Jack, 23, Fubara George, 22, Precious Wokoma, 20, Dennis Lugard, 53 ati Alalibo Harry, 32.

Nigbati oun ba awọn oniroyin sọrọ ọmọ ti wọn fipa ba lopo lọna aito ni awọn afurasi naa ni ọkọ iya oun, oluko kilaasi ileeko rẹ, pasitọ sọọsi rẹ niluu Buguma, nipinlẹ Rivers, ati awọn ọdọ meji ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi awọn ọmọ iṣọta.

O sọ pe gbogbo awọn ẹniyan mararun-un naa ni oriṣiriṣi igba ti fi ọna aito ba oun lopọ lati igbati oun wa ni ọdun mẹfa.

Adajo agba, Menen Poromon, leyin ti o gbo ẹjo awọn olugbejoro lori ọrọ naa, sun igbejọ ṣiwaju fun awọn afurasi naa lati sọ tẹnu wọn ati lati gba beeli awọn afurasi naa.