Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ máleègbàgbé tó ṣẹlẹ̀ lágbo erè ìdárayá Nàìjíríà lọ́dún 2022

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ ọmọ bibi Orilẹ-ede Naijiria ni o nifẹ si ere idaraya ati pe awọn ara ilu fẹran lati ri awọn ọmọ orilẹede yii yege ninu awọn ere idaraya ti wọn kopa ninu rẹ.
Bi ọdun 2022 ṣe n lọ sopin Bbc news Yoruba ṣe akojopo diẹ lara awọn ere idaraya nibiti orilẹede Naijiria ti yege ati awọn ibiti Naijiria ti kuna lati kopa tabi bori.
Idije Bọọlu
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles kopa ninu idije ifee ẹyẹ ilẹ Afrika eyiti orilẹede Cameroon gba alejo rẹ.
Bo tile jẹ wi pe ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles pegede ninu isori ti wọn wa lai sọ ayo kankan nù.
Ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Tunisia ni ó fi ọwọ osi juwe ilẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles pẹlu amin ayo kan sì odo ni isori quarter final.

Oríṣun àwòrán, Others
Kini o ṣẹlẹ laarin ẹgbẹ Flamingo ni 2022?
Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Flamingo ninu idije agbaye fun awọn obinrin ti o ju ọdun mẹta din logun lo bori orilẹede Germany ninu ipele ẹniti o ṣe ipo kẹta.
Wọn bori orilẹede Germany ninu idije ẹniti yoo gba ipo kẹta pẹlu amin ayoo mẹta si meji.
Bakan naa Ikọ agbabọọlu Super Eagles kuna lati pegede lati kopa ninu idije ifee ẹyẹ agbaye to waye ni orilẹede Qatar,
Nigba ti Iko Black stars ti Ghana jawo Ikọ Super Eagles kuro ninu idije naa ni olu-ilu orilẹede yii Abuja lẹyin ti wọn gba amin ayo kokan pẹlu Ikọ Black Stars ti Ghana.
Awon Super Falcons nko?
Ẹgbẹ Agbabọọlu Super Falcons fun igba akọkọ kuna lati gba amin ẹyẹ kankan ninu idije ifee ẹyẹ fun awọn agbabọọlu obinrin nilẹ Africa.
Iko agbabọọlu obinrin Zambia fi amin ayo kan lu Super Falcons,bo tile jẹ wi pe wọn pegede lati soju Afrika ninu idije fun awọn agbabọọlu obinrin agbaye.
Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu flamingo ninu idije agbaye fun awọn obinrin ti o ju ọdun mẹta din logun lo bori orilẹede Germany ninu ipele ẹniti o ṣe ipo kẹta.
Wọn bori orilẹede Germany ninu idije ẹniti o gba ipo kẹta pẹlu amin ayoo mẹta si meji.

Oríṣun àwòrán, Others
Ìdíje ẹsẹ kíkan ni 2022?
Anthony Joshua ninu erongba rẹ lati dabo bo bante ẹsẹ kikan kuno lẹmeji nigbati Oleksandr Usyk lati ukraine lẹmeji fi iyajee.
Bakan naa ni Kamaru Usman ri iya ee lọwọ Leon Edwards ninu ẹsẹ ati akatakiti ija (mix Martial) ninu oṣu kẹjọ ọdun yii,
pẹlu gbogbo akitiyan Kamaru Usman lati fakoyo lọ ja si pabo nigba ti Leon Edwards fi ipa gbe e lule to si sọ bante rẹ nu.

Oríṣun àwòrán, others
Ìdíje Èrè sisa lorí pápá.
Tobi Amusan di ọmọ orilẹede Naijiria akoko lati bori ninu idije ere idaraya orí papa ti o si ko akọsilẹ titun pẹlu iseju 12:12 ninu idije ere sisa.
Ní ìparí
Ere idaraya ni Naijiria ninu ọdun 2022 ri ọpọlọpọ ijakulẹ latari bi ọpọlọpọ awọn aṣoju orilẹede yii se kuna lati bori ninu awọn idije ti wọn kopa ninu rẹ.
Ṣugbọn ireti wa pe ọdun 2023 yoo larinrin fun awọn ọmọ orilẹede yii ninu ere idaraya.

Oríṣun àwòrán, Others












