Owó oúnjẹ ni mo lọ ọ gbà, oyún ọmọ tí mo jù sí àkìtàn ni mó gbé wálé- Dupe, ìyá Muiz

Ti gbogbo obinrin ba loyun, adura wa a bi wẹrẹ, wa ri ọmọ gbejo ni diẹ lara adura ti awọn eeyan ma n gba fun wọn.
Ṣugbọn ni ti Arabinrin Dupe Alabi, ko ri bẹ o. Ori akitan lo ju ọmọ si, lẹyin to ru ẹru oyun fun oṣu mẹsan-an.
Ẹyin naa kọ ha! Ṣugbọn ṣebi ti ko ba nidi, obinrin kii jẹ kumolu.
BBC tẹkọ leti lọ silu Ogbomọsọ, nipinlẹ Oyo, lati ba Dupe sọrọ, nkan to fa igbesẹ rẹ to sọ kọja bẹẹ.
- Àwọn dókítà yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódí lọ́jọ́ Ajé
- Wo ọ̀nà ìsanwó tuntun fún àwọn oníbárà iná mọ̀nàmọ́ná ní Eko (EKDC)
- Nàìjíríà làwọn ní ìfẹ́ sí ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Russia ṣe
- Níbo lọ̀rọ̀ dé dúró nípa iṣẹ́ àwọn tó n wa iṣẹ́ N-Power?
- Èsì ìdánwò òhun tí a ṣé síwájú là n bá fínra báyìí ní Nàìjíríà- Yemi Shodimu
Dupe ni "bi mo ṣe bi i tan, mi o tiẹ wo boya ọkunrin ni tabi obinrin. Mo kan gbe ju si ibi ti wọn ti gbe e ni.
Mo wa duro nitosi ibẹ, lati wo boya ẹnikẹni yoo gbe. Ero ọkan mi ni pe ti wọn ba gbe, wọn o ni le mọ pe emi ni mo ju ọmọ sibẹ.
Ọmọ tuntun yii kọ ni akọkọ fun Dupe. O ti bi ọmọ mẹrin tẹlẹ, fun ọkunrin meji.
O sọ fun BBC pe ipọnju ati idaamu lo mu ki oun gbe ọmọ ẹlẹẹkarun sọnu.
Itiju ni oyun ọmọ naa jẹ fun mi, nitori ipo ti mo wa. Mo si fi aṣiri oyun naa pamọ, debi pe ti awọn eeyan ba beere pe ṣe mo loyun, ma a sọ pe rara.
Lati inu oyun ni mo ti pinnu pe, ma wa ibi kan ju u si ti mo ba bi. Nitori naa, ni mi o ṣe ra nkan ọmọ kankan.
Arabinrin Dupe ṣalaye pe ija ati idaamu lo mu oun kuro nile ọkọ oun akọkọ. Ibi to si ti n ṣe ọmọọdọ olounjẹ lo ti pade ọkunrin keji, to bi ọmọ meji fun.
Ile ọkunrin keji yii lo wa, ti baba ọmọ rẹ akọkọ tun fi n fẹ ko pada si ọdọ rẹ.
"Ti ọkọ mi akọkọ ba pade mi lọna, yoo ma sọ fun mi pe ki n ko pada si ọdọ rẹ. Ṣugbọn, mo ma n sọ fun pe ko ṣe e ṣe."
"Iroyin yii ni ẹnikeji ti mo fẹ n gbọ, to fi ko kuro ninu ile ti a jọ n gbe, to si fẹ obinrin mii. O ni oun gbọ pe ọkọ mi akọkọ sọ pe oun yoo gba mi pada."
Dupe ko pada si ile awọn obi rẹ ni Odo Ọba. Ibẹ si lo wa ti ọkọ rẹ akọkọ tun fi n fa oju rẹ mọra.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, ọkọ rẹ akọkọ ṣeleri fun lati tọju rẹ pẹlu ọmọ mẹtẹẹta. Eyi si lo mu ki Dupe ko pada si ile rẹ.
Awọn mejeeji jọ n gbe papọ,koda, Dupe tun bimọ kan fun.
Ṣugbọn "nigba to ya, o bẹrẹ si ni ba mi ja pe ki n ko awọn ọmọ meji ti mo bi fun ọkunrin keji pada si ọdọ baba wọn.
"Ija yii pọ debi i pe, awọn obi mi wa ba mi ko ẹru mi kuro nile rẹ."
Dupe ati ọkọ rẹ yii ko rira fun bi ọdun kan aabọ, nitori pe onitọhun rinrinajo kuro niluuu.
Dide to de pada, o ranṣẹ si Dupe pe ko wa a gba owo ounjẹ fun ọmọ rẹ ọkunrin to bi fun.
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ọkùnrin kan da ṣọ́ọ̀ṣì rú lásìkò ìgbéyàwó, Ó ní òun lọkọ àárọ̀ ìyàwó tuntun
- Èèmọ̀! Ọmọbìnrin ọdún 25 gún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa nítorí ó ní ko lọ ṣẹ́ oyún
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ìwọ́de l'Osogbo lórí àfikún owó epo bẹntiróò
- Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele
Owo ounjẹ ni Dupe lọ ọ gba, oyun ọmọ karun-un lo gbe pada sile.
"Nigba ti mo ri i pe mo loyun, mo gbiyanju lati sọ fun, ṣugbọn mi o ri nitori pe o tun ti kuro niluu.
"Iyalẹnu ni pe o ṣọ fun awọn eeyan rẹ to ri i pe oun kọ lo fun mi loyun."
Ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020, ni ọmọ bẹrẹ sini mu Dupẹ, ko sọ fun ẹnikẹni, nitori pe 'wọn o mọ pe o loyun'.
"Ni nkan bi aago mọkanla alẹ ni ọmọ bẹrẹ si ni i mu mi. Mi o sọ fun ẹnikankan, nitori pe mo ti ma n sọ fun wọn tẹlẹ pe ikun mi kan n wu ni, kii ṣe oyun lo wa nibẹ, ni gba ti wọn ba beere pe ṣe mo loyun.
"Mo rọra bọ si inu ile kan to wa ni ẹgbẹ ileewosan Akala, ni Oke Elerin, nilu Ogbomọṣọ."
Wọn ti maa n wọ inu ile naa tẹlẹ lati ṣe igbọnsẹ.
"Bi ọmọ naa ṣe jabọ, mi o ti ẹ wo boya ọkunrin ni, tabi obinrin. Mo kan gbe, mo si ju u si ibi ti awọn oṣiṣẹ ileewosan ti ri."
Pipada to pada sinu ile, ni ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbele, fi ẹsun kan an pe "Iya Muiz, ṣe ẹyin kọ lẹ gbe ọmọ ju si akitan ni?
"Mo tiẹ kọkọ fẹ ẹ ma a sọ pe mi o bi ọmọ kankan, ṣugbọn o sọ fun mi pe awọn obi mi ti wa pẹlu ọmọ ni ileewosan.
"Bi mi o ṣe le jiyan mọ niyii, mo si bẹrẹ si ni sunkun."
Arabinrin Dupe ṣalaye pe oun ni akọbi iya ati baba oun, to si jẹ pe ọmọ mejidinlogun ni baba rẹ bi.
O ni itiju ko fẹ ẹ jẹ ki oun lọ ma a gbe pẹlu iya oun, nitori pe awọn iyawo aburo oun n gbe pẹlu rẹ.
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Ó sàn kí ẹ pa mí ju kí ẹ ba oko tí mo gbin igbó sí jẹ́ lọ- Afurasi Clement sí NDLEA
- A kú oríire! Oró agbọ́n leè wo àìsàn jẹjẹrẹ ọmú sàn, wo ohun tí wàá lò pọ̀ mọ́ra wọn
- Ara ló ń ta àwọn ẹgbẹ́ NURTW tó ń pariwo mi kiri, APC ni wọ́n bá lọ nígbà náà l'Oyo- Auxiliary
Alaga ijọba ibilẹ idagbasoke Ogbomoso Central, Adeyinka Remi Oluwaseun, sọ fun BBC pe oun ti gba obinrin naa siṣẹ nileeṣẹ ijọba.
"Aanu rẹ ṣe mi, bi mo ṣe ri i pe ọmọ marun lo ti bi, lai si iṣẹ tabi ọkọ ti yoo tọju rẹ.
"Awọn oṣiṣẹ wa tọju rẹ nileewosan, mo si tun ti ṣeleri pe ma a tọju ọmọ naa titi de ileewe girama."
Adeyinka Oluwaseun Moraanugba ni wọn sọ ọmọ tuntun naa.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí olóògùn owó tó fẹ́ gé ọmú obìnrin kan nílé ìtura
- Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo gbarata lórí àlékún owó epo bẹntiróò
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Wo àwọn òfin tuntun tíjọba fí síta lórí lílọ ìrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ìwọ́de l'Osogbo lórí àfikún owó epo bẹntiróò


















