Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọ́lù ú

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Bi o ba lo ọdun mẹtadinlogun lọgba ẹwọn lori 'ẹṣẹ aimọdi, Ta ni o maa pe lẹjọ?

Irinajo Adebayo Ojo lati ilu Ọgọtun Ekiti ni BBC Yoruba mu wa loni.

Adebayo to n ṣiṣẹ oko alagbaṣe fi ran ara rẹ nile iwe titi to fi kawe de ile iwe giga Owo Poly lo ko sọwọ agbofinro lori ẹṣẹ aimọdi to si ti ibẹ gba idajọ iku.

O ni wọn ni oun digunjale pẹlu awọn awọn eeyan kan lati ja Omolade Yemi lole, eyi to sọọ di ero SARS

Adebayo Ojo ni lati Ilawẹ Ekiti lọ si ọgba SARS ni Ado Ekitit ko to di ero Maximum Security Prison ni eko ni irinajo yii

O ni lọdun 2003 ni oun ti ko sii ko to bọ ni 2019.

2005 ni wọn dajọ iku fun un, ṣugbọn gomina Fayose ni oun ko le bu ọwọ lu iwe iku ẹlomii.

Tomale Akinbanji, to jẹ ọrẹ Ojo sọrọ ilẹ kun fun BBC lori iṣẹlẹ arinfẹsẹsi yii.

Adebayo Orisameyitimi to jẹ baba Ojo ni Ọgọtun Ekiti naa sọrọ pe diẹ lo ku ki oun ku nitori airi owo gba lọya fun Ojo

Ọjo ṣalaye bi o ṣe kawe pada lati J S 3 pẹlu iranlọwọ Cottage of Hope Institute ninu ọgba ẹwọn to fi kawe gboye jade ninu Criminology ni National Open University .

Ojo sọ ipa ti Al-Mustapha kó fun oun nigba ti wọn jọ wa lẹwọn ati ajọ JLAA ati agbẹjọrọ Kingsley Ughe Esq tó pada kọwe si gomina Fayemi nigba to de ori aleefa.

Gomina Fayemi lo pada tu Ojo silẹ pẹlu agba ra ipo rẹ.

Gbogbo eeyan n beere iranlọwọ iṣẹ fun Ojo Adebayọ lasiko yii.