N10m suit: Agbẹjọ́rọ̀ ọmọ Nàìjíríà, Ogedi Ogu gbé Fásitì Oxford lọ sílé ẹjọ́ lórí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Eko ti da ẹjọ ti Oxford ti pe tako ipẹjọ oni miliọnu mẹwaa Naira ti agbẹjọro ọmọ Naijiria Ogedi Ogu pe tako wọn nu.
Ogu ninu ějọ to pe niwaju adajọ I.O. Harrison, ti salaye pe itumọ ọrọ ti wọn fun "mortgagee" ati "mortgator ninu iwe atumọ ọrọ Oxford ti ile itẹwe Oxford Press ki se eyi to tẹwọn rara.
O ni o jẹ nkan itiju fun oun nigba ti oun kuna gẹgẹ bi agbẹjọro, o si tabuku ba isẹ nigba ti oun gbara le itumọ ọrọ inu "Oxford Dictionary " lati gba alabaṣiṣẹpọ oun ni imoran ni ilana isẹ wọn ti o si ja si pe awọn itumọ naa ko tọna to.
O ni alabasisẹ pọ oun lo wa naka si i pe itumọ ti "Oxford Dictionary" kọ kii ṣe eyi to mu itumọ pipe jade ati pe lati igba naa, awọn alajumọ ṣiṣẹ pọ oun kii bere ibere tabi imọran to ba jẹ mọ isẹ lọwọ oun mọ
Ogu rọ ile ẹjọ lati sọ fun Fasiti Oxford ati ile itẹwe Oxford lati san miliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran ati bibani lorukọ jẹ.
Ṣugbọn agbẹjọro fun Oxford, arabinrin Funke Adekoya (SAN) naa ti kọwe lodi si ipẹjọ naa pe ko ni ẹri to peye ati pe ki ile ẹjọ da ipẹjọ naa nu.
Adekoya ni Ogu ko tẹle ilana iwe ofin ti "Sheriff and Civil Process Act" ko to kọ iwe ipẹjọ naa.
O sapejuwe ipẹjọ naa gẹgẹ bi eyi ti ko ni itumọ kan kan, ohun a n gbe pati si ẹgbẹ kan ni
Agbẹjọro agba naa fi kun un pe ile itẹwe Fasiti Oxford, ti o fi kun un bi olujẹjọ keji ko ni ejọ ọ ro rara nitori ẹka lasan ni nile ẹkọ fasiti Oxford, ko le da duro fun ijẹjọ.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí iléèwé
- Iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust gbọdọ̀ san N6 bilion nítorí ìbanilórúkọjẹ́- Femi Fani Kayode
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Bí ìjà bá wà láàrin èmi àti Olubadan, a ó yanjú ẹ ní pẹ̀lẹ́kùtù, ọ̀rọ̀ bàbálọ́jà kò lè dìjà
Ṣugbọn ọgbọn ọjọ, ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, Adajọ Harrison tako arabinrin Adekoya ni apa ibikan to si da iwe ẹbẹ pe ki ile ẹjọ ma sọrọ lori igbẹjọ naa nu.
Yatọ si ọrọ Adekoya pe ipẹjọ naa mẹhẹ Adajọ Harrison ni ẹjọ naa tọna, o si yanranti, o ba ofin mu, kii si ṣe nkan to yatọ rara si awọn ipẹjọ to ti maa n waye tẹlẹ.
Sugbọn Adajọ naa gba pe lootọ ni ẹka ni ile itẹwe Oxford jẹ ko si le duro fun ijẹjọ nitori naa ki wọn yọ kuro ninu igbẹjọ naa.
















