Olusegun Obasanjo: Ibrahim Ibuoye, ẹni ọgọ́ta ọdún dèrò ilé ẹjọ́ nítorí ó wọ inú oko Obasanjo láì gba àṣẹ

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹni ọgọta ọdun Ibrahim Ibuoye to foju bale ẹjọ majisireeti kan ni ipinlẹ Ogun nitori o wọ oko aarẹ orile-ede Naijiria nigba kan ri Olusegun Obasanjo ni Ota lai gba aṣẹ.

Ẹsun mẹrin ni wọn fi kan Ibuoye lbrahim, o da omi alaafia agbegbe naa ru, o fi tipa wọ ori ilẹ onilẹ, o ba n kan jẹ, o si tun gbimọ ọtẹ, eyi to si ti ni oun ko jẹbi ikankan ninu awọn ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Insipẹkitọ ọlọpaa to wa nidi ọrọ naa, Rosemary Samson sọ fun ile ẹjọ pe ẹni a fẹsun kan yii ati awọn miran to ti salọ lo jọ ṣe ẹsẹ naa ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 ni Obasanjo Farm Ltd Ota.

Samson ni ọkunrin ohun ati awọn ẹmẹwa rẹ mu nkan ija lọwọ, ti wọn si fi agidi wọ inu oko naa ti o si da ipaya silẹ laarin awọn eniyan, eyi tumọ si pe wọn da omi alaafia ibẹ ru.

Bakan naa ni o ni ọkunrin ohun ba mọto Hinda Accord pelu ami idanimọ LSD 655 EV, to jẹ ti Kazeem Ajiboye jẹ pẹlu.

Ọlọpaa naa fi kun un pe eyi tako ofin Criminal Code ipinlẹ Ogun, ọdun 2006

Adajọ Majisirati oun B. S Abdulsalm gba pe ki wọn gba oniduro fun ọkun rin naa pẹlu ẹgbrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira gẹgẹ bi owo itanran, pẹlu oniduro meji.

Àkọlé fídíò, Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo

Abdulsalam fi kun un pe, awon oniduro rẹ gbodọ jẹ olugbe adugbo ile ẹjọ ki o si ni iṣẹ gidi lọwọ pẹlu ẹri iwe owo oei to n san deede fun ijọba ipinlẹ Ogun.

Ile ẹjọ tun pa a lașẹ pe oniduro naa gbọdọ ni ilẹ ni ayika ibi ti ile ẹjọ Majisisreeti ohun wa pẹlu ki wọn to le gba oniduro fun.

Wọn ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla oṣu yii.