Baba Obasanjo: Àwọn ọ̀rẹ̀ sàpèjúwe Baba Obasanjọ ní ọjọ́ ìbí 83 wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn agbaagba nilẹ Yoruba ti sapejuwa aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi ẹbùn rere ni Baba Obasanjọ jẹ fun Naijiria.
Akowe ẹgbẹ Yoruba Council of Elders (YCE), Kunle Olajide lo ṣe apejuwe Baba Obasanjọ bẹẹ lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi pe wọn pe ẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Olajide ni oun ko i tii ri ẹni to fẹran orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ọkan soso to Baba Obasanjọ nitori wọn ja fitafita lati ri wi pe orilẹede Naijiria wa papọ lai si ipinya.
O fikun pe ọkunrin takuntakun ni Baba Obasanjọ, ti o laya ti kosi bẹru lati sọ otitọ fun ẹnikẹni.
Ninu ọrọ rẹ ẹgbẹ agba ni ilẹ Yoruba ni Obasanjọ kii se ẹlẹyamẹya, bẹẹ ni kii fun eniyan ni iṣẹ tabi fi ẹni si ipo nitori wọn jẹ ẹya kan naa, eleyii to tako iwa wobiliti wọbia to wọpọ bayii ni awujọ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kunle Olajide ni Baba Obasanjọ ni ọgbọn to bẹẹ gẹ ti ko jẹ ijọba ologun tun gba ijọba lẹyin ti o ṣẹ ijọba alagbada fun ọdun mẹjọ lati ọdun 1999 si 2007.
Amọ, o gba baba niyanju lati mu ki ọrọ ilẹ Yoruba jẹ ẹ logun, ki o si ba wọn gbe ọrọ atuntọ orilẹede Naijiria lọ si awọn ibi giga ti wọn ti n fọhun, ki orilẹede Naijria le di atunto.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, Arakunrin Babablola Ogunbuyide to jẹ gẹgẹ bi ọrẹ ati ọmọ si Baba ọbasanjọ naa ṣẹ apejuwe rẹ ẹni rẹrẹ ti Olorun ṣẹda rẹ.
Ogunbuyide wa tẹsiwaju lati sọ ohun ti awọn eniyan ko mọ nipa Baba Obasanjo:
- Oni inu ire to si ni ifẹ awọn eniyan
- Baba Obasanjọ ni ọgbọn lati tun nkan to nibikibi ti o ba wa.
- Oun wuwa si ni gẹgẹ bi ọmọ lai fasẹyin fun ẹnikẹni to ba tọ ọ wa.
- Baba Obasanjo kii fi ọwọ rọ ẹnikẹni sẹyin tabi da ọrọ wọn nu.
- Baba kii binu nitori eniyan ṣe aṣiṣe, amọ o fẹran ki eniyan mọ ẹbi rẹ ni ẹbi,ki o si ṣe atunsẹ.
Eyi ni akojọpọ aworan ere itage itan Baba Oluṣegun Obasanjọ:








Awọn aworan yii wa lati ileeṣẹ BBC News Yoruba













